Esek 47 YCE

1 O si mu mi padà wá si ibi ilẹkùn ile na; si kiyesi i, omi ntù jade lati abẹ iloro ile na nihà ila-õrun: nitori iwaju ile na wà ni ila-õrun, omi si nwalẹ lati abẹ apa ọtun ile na, ni gusu pẹpẹ.

2 O si mu mi jade ni ọ̀na ẹnu-ọ̀na ihà ariwa, o si mu mi yi wá ọ̀na ode si ẹnu-ọ̀na ode ni ọ̀na ti o kọjusi ila-õrun; si kiyesi i, omi ṣàn jade lati ihà ọtun.

3 Nigbati ọkunrin na jade sihà ila-õrun, pẹlu okùn kan lọwọ rẹ̀, o si wọ̀n ẹgbẹrun igbọnwọ, o si mu mi là omi na ja; omi na si de kókosẹ̀.

4 O tun wọ̀n ẹgbẹrun, o si mu mi là omi na ja; omi na si de ẽkun. O si wọ̀n ẹgbẹrun, o si mu mi là a ja; omi si de ẹgbẹ́.

5 O si wọ̀n ẹgbẹrun; odò ti nkò le wọ́: nitori omi ti kún, omi ilúwẹ, odò ti kò ṣe rekọja.

6 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, Iwọ ri yi? O si mu mi wá, o si mu mi pada wá si bèbe odò na.

7 Nigbati mo pada, si kiyesi i, igi pupọ̀pupọ̀ wà ni ihà ihin ati ni ihà ọhun li eti odò na.

8 O si wi fun mi pe, Omi wọnyi ntú jade sihà ilẹ ila-õrun, nwọn si nsọkalẹ lọ si pẹ̀tẹlẹ, nwọn si wọ̀ okun lọ: nigbati a si mu wọn wọ̀ inu okun, a si mu omi wọn lara dá.

9 Yio si ṣe pe, ohunkohun ti o ba wà lãye ti nrakò, nibikibi ti odò mejeji ba de, yio wà lãye: ọ̀pọlọpọ ẹja yio si de, nitori omi wọnyi yio de ibẹ̀: a o si mu wọn lara dá; ohun gbogbo yio si yè nibikibi ti odò na ba de.

10 Yio si ṣe pe, Awọn apẹja yio duro lori rẹ̀ lati Engedi titi de Eneglaimu; nwọn o jẹ ibi lati nà àwọn si; ẹja wọn o dabi iru wọn, bi ẹja okun-nla, lọpọlọpọ.

11 Ṣugbọn ibi ẹrẹ̀ rẹ̀ ati ibi irà rẹ̀ li a kì o mu laradá; a o fi nwọn fun iyọ̀.

12 Ati lẹba odò ni eti rẹ̀, ni ihà ihin ati ni ihà ọhun, ni gbogbo igi jijẹ yio hù, ti ewe rẹ̀ kì yio rọ, ti eso rẹ̀ kì yio si run: yio ma so eso titun rẹ̀ li oṣù rẹ̀, nitori omi wọn lati ibi mimọ́ ni nwọn ti ntú jade: eso rẹ̀ yio si jẹ fun jijẹ, ati ewe rẹ̀ fun imunilaradá.

13 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; eyi ni yio jẹ ãlà, ti ẹnyin o fi jogún ilẹ na fun ara nyin fun ẹ̀ya mejila Israeli: Josefu yio ni ipin meji.

14 Ẹnyin o si jogún rẹ̀, olukuluku bi ti ekeji rẹ̀: eyiti mo ti gbe ọwọ́ mi sokè lati fi i fun awọn baba nyin: ilẹ yi yio si bọ sọdọ nyin fun ogún.

15 Eyi ni yio si jẹ ãlà ilẹ na nihà ariwa, lati okun nla, ni ọ̀na Hetloni, bi a ti nlọ si Sedadi;

16 Hamati, Berota, Sibraimu, ti o wà lãrin ãlà Damasku, ati ãlà Hamati; Hasar-hatikonu, ti o wà ni agbègbe Haurani.

17 Alà lati okun yio si jẹ Hasarenani, ãlà Damasku, ati ariwa nihà ariwa, ati ãlà Hamati. Eyi si ni ihà ariwa.

18 Ati ni ihà ila-õrun ẹ o wọ̀n lati ãrin Haurani, ati lati ãrin Damasku, ati lati ãrin Gileadi, ati lati ãrin ilẹ Israeli lẹba Jordani, lati ãlà titi de okun ila-õrun. Eyi ni ihà ila-õrun.

19 Ati ihà gusu si gusu, lati Tamari titi de omi ijà ni Kadeṣi, pẹ̀tẹlẹ si okun nla. Eyi ni ihà gusu.

20 Ihà iwọ-õrun pẹlu yio jẹ okun nla lati ãlà bi a ti nlọ si Hamati. Eyi ni ihà iwọ-õrun.

21 Bayi li ẹ o pin ilẹ yi fun ara nyin gẹgẹ bi awọn ẹ̀ya Israeli.

22 Yio si ṣe pe, ìbo ni ẹ o fi pin i ni ogún fun ara nyin, ati fun awọn alejo ti o ṣe atipo lãrin nyin, ti nwọn bi ọmọ lãrin nyin: nwọn o si ri si nyin bi ibilẹ ninu awọn ọmọ Israeli; nwọn o ba nyin pin i li ogún lãrin awọn ẹ̀ya Israeli.

23 Yio si ṣe pe, ni ẹ̀ya ti alejò ba ṣe atipo, nibẹ̀ li ẹ o fun u ni ogún, ni Oluwa Ọlọrun wi.