Esek 30 YCE

1 Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

2 Ọmọ enia, sọtẹlẹ ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹ wu, Egbé fun ọjọ na!

3 Nitori ọjọ na sunmọ tosí, ani ọjọ Oluwa sunmọ tosi, ọjọ ikũkũ ni; yio jẹ akoko ti awọn keferi.

4 Idà yio si wá sori Egipti, irora nla yio wà ni Etiopia, nigbati awọn ti a pa yio ṣubu ni Egipti, nwọn o si mu ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ lọ kuro, ipilẹ rẹ̀ yio si wó lulẹ.

5 Etiopia, ati Libia, ati Lidia, ati gbogbo awọn olùranlọ́wọ, ati Kubu, ati awọn enia ilẹ na ti o mulẹ yio ti ipa idà ṣubu pẹlu wọn.

6 Bayi li Oluwa wi; Awọn pẹlu ti nwọn gbe Egipti ró yio ṣubu; ati igberaga agbara rẹ̀ yio sọkalẹ: lati Migdoli lọ de Siene ni nwọn o ti ipà idà ṣubu ninu rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.

7 Nwọn o si di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ilu rẹ̀ yio si wà li àrin awọn ilu ti o di ahoro.

8 Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo bá gbe iná kalẹ ni Egipti, ti gbogbo awọn olùranlọ́wọ rẹ̀ bá parun.

9 Li ọjọ na ni onṣẹ yio lọ lati ọdọ mi ninu ọkọ̀, lati dẹ̀ruba Etiopia ti o wà li alafia, irora yio wá sori wọn gẹgẹ bi li ọjọ Egipti: kiyesi i, o de.

10 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o si ṣe ki ọ̀pọlọpọ enia Egipti ki o ti ipa ọwọ́ Nebukaddressari ọba Babiloni dínkù.

11 On ati enia rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ẹ̀ru awọn orilẹ-ède, li a o mu wá pa ilẹ na run: nwọn o si fà idà wọn yọ si Egipti, nwọn o si fi awọn ti a pa kún ilẹ na.

12 Emi o mu gbogbo odò wọn gbẹ, emi o si tà ilẹ na si ọwọ́ awọn enia buburu; emi o si ti ipa ọwọ́ awọn alejo sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹkún rẹ̀: Emi Oluwa li o ti sọ ọ.

13 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o pa awọn oriṣa run pẹlu, emi o si jẹ ki ere wọn tán ni Nofi; kì yio si si ọmọ alade kan ni ilẹ Egipti mọ́: emi o si fi ẹ̀ru si ilẹ Egipti.

14 Emi o si sọ Patrosi di ahoro, emi o si gbe iná kalẹ ni Soani, emi o si mu idajọ ṣẹ ni No.

15 Emi o si dà irúnu mi si ori Sini, agbara Egipti; emi o si ké ọ̀pọlọpọ enia No kuro.

16 Emi o si gbe iná kalẹ ni Egipti, Sini yio ni irora nla, a o si fà No ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, Nofi yio si ni ipọnju lojojumọ.

17 Awọn ọdọmọkunrin Afeni ati Pibeseti yio ti ipa idà ṣubu: ati awọn wọnyi yio lọ si igbèkun.

18 Ọjọ yio si ṣõkun ni Tehafnehesi, nigbati emi bá dá àjaga ọrùn Egipti nibẹ: ọṣọ́ agbara rẹ̀ yio tán ninu rẹ̀: bi o ṣe tirẹ̀ ni, ikũkũ yio bò on, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin yio lọ si igbèkun.

19 Bayi li emi o mu idajọ ṣẹ ni Egipti: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

20 O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣù kini, li ọjọ keje oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

21 Ọmọ enia, emi ti ṣẹ apá Farao ọba Egipti; si kiyesi i, a kì yio dì i ki o ba le san, bẹ̃ni a kì yio fi igi si i lati dì i ki o ba lagbara lati di idà mu.

22 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, emi dojukọ Farao ọba Egipti, emi o si ṣẹ́ apá rẹ̀, eyi ti o le, ati eyiti o ṣẹ́; emi o si jẹ ki idà bọ́ kuro li ọwọ́ rẹ̀.

23 Emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin awọn orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin ilẹ.

24 Emi o si mu apá ọba Babiloni le, emi o si fi idà mi si ọwọ́ rẹ̀: ṣugbọn emi o ṣẹ́ apá Farao, yio si ma kerora niwaju rẹ bi ikérora ọkunrin ti a ṣá li aṣápa.

25 Ṣugbọn emi o mu apá ọba Babiloni le, apá Farao yio si rọ; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ba fi idà mi si ọwọ́ ọba Babiloni, ki o le ba nà a sori ilẹ Egipti.

26 Emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin awọn orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin awọn ilẹ; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.