1 Ọ̀RỌ Oluwa tún tọ̀ mi wá, wipe,
2 Ọmọ enia, doju kọ awọn ara Ammoni, si sọtẹlẹ si wọn;
3 Si wi fun awọn ara Ammoni pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun: Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti iwọ wipe, Aha, si ibi mimọ́ mi, nigbati o di àilọwọ, ati si ilẹ Israeli, nigbati o di ahoro; ati si ilẹ Juda, nigbati nwọn lọ ni ìgbekun;
4 Kiyesi i, nitorina emi o fi ọ le awọn enia ilà-õrùn lọwọ fun ini, nwọn o si gbe ãfin wọn kalẹ ninu rẹ, nwọn o si ṣe ibugbe wọn ninu rẹ: nwọn o jẹ eso rẹ, nwọn o si mu wàra rẹ.
5 Emi o si sọ Rabba di ibujẹ fun ibakasiẹ, ati awọn ọmọ Ammoni di ibùsun fun agbo-ẹran: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
6 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti iwọ ti pa atẹ́wọ, ti o si ti fi ẹsẹ kì ilẹ, ti o si yọ̀ li ọkàn pẹlu gbogbo aránkan rẹ si ilẹ Israeli:
7 Kiye si i, nitorina, emi o nà ọwọ́ mi le ọ, emi o si fi ọ fun awọn keferi fun ikogun; emi o si ke ọ kuro lãrin awọn enia, emi o si jẹ ki o ṣegbé kuro ninu ilẹ gbogbo: emi o pa ọ run; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
8 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe Moabu ati Seiri wipe, Kiye si i, ile Juda dabi gbogbo awọn keferi;
9 Nitorina, kiye si i, emi o ṣi ìha Moabu kuro lati awọn ilu gbogbo, kuro ninu awọn ilu rẹ̀ ti o wà li àgbegbe rẹ̀, ogo ilẹ na, Bet-jeṣimoti, Baalimeoni, ati Kiri-ataimu,
10 Fun awọn ọmọ ìla-orun, pẹlu awọn ara Ammoni, emi o si fi wọn fun ni ni iní; ki a má ba ranti awọn ara Ammoni lãrin orilẹ-ède mọ.
11 Emi o si mu idajọ ṣẹ si Moabu lara, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
12 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe Edomu ti huwà si ile Juda nipa gbigba ẹsan, o si ti ṣẹ̀ gidigidi, o si gbẹ̀san ara rẹ̀ lara wọn.
13 Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi pẹlu yio nawọ mi si Edomu, emi o si ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀; emi o si sọ ọ di ahoro lati Temani; ati awọn ti Dedani, yio ti ipa idà ṣubu.
14 Emi o si gbe ẹ̀san mi le ori Edomu lati ọwọ́ Israeli enia mi: nwọn o si ṣe ni Edomu gẹgẹ bi ibinu mi, ati gẹgẹ bi irúnu mi; nwọn o si mọ̀ ẹ̀san mi, li Oluwa Ọlọrun wi.
15 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti awọn ara Filistia ti lò ilo ẹsan, ti nwọn si ti fi ọkàn ti o kún fun arankàn gbẹsan, lati pa a run, nitori irira atijọ.
16 Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o nà ọwọ́ mi le awọn ara Filistia, emi o si ke awọn ara Keriti kuro, emi o si run awọn iyokù ti eti okun.
17 Emi o si san ẹsan nla lara wọn nipa ibáwi gbigbona; nwọn o si mọ̀ pe, emi li Oluwa, nigbati emi o gbe ẹsan mi le wọn.