Esek 32 YCE

1 O si ṣe li ọdun kejila, li oṣù kejila, li ọjọ ikini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

2 Ọmọ enia, pohunrére fun Farao ọba Egipti, si wi fun u pe, Iwọ dabi ẹgbọ̀rọ kiniun awọn orilẹ-ède, iwọ si dabi dragoni ninu okun, iwọ si jade wá pẹlu awọn odò rẹ, iwọ ti fi ẹsẹ rẹ rú omi, o si ti bà awọn odò wọn jẹ́.

3 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitorina emi o nà àwọn mi sori rẹ pẹlu ẹgbẹ́ enia pupọ̀; nwọn o si fà ọ goke ninu àwọn mi.

4 Nigbana ni emi o fi ọ silẹ lori ilẹ, emi o gbe ọ sọ sinu igbẹ́, emi o mu ki gbogbo awọn ẹiyẹ oju ọrun ba le ọ lori, emi o si fi ọ bọ́ gbogbo awọn ẹranko aiye.

5 Emi o gbe ẹran ara rẹ kà awọn ori oke, gbogbo afonifoji li emi o fi giga rẹ kún.

6 Emi o si fi ẹ̀jẹ rẹ rin ilẹ nibiti iwọ nluwẹ́, ani si awọn oke; awọn odò yio si kún fun ọ.

7 Nigbati emi o ba mú ọ kuro, emi o bò ọrun, emi o si mu ki awọn ìrawọ inu rẹ̀ ṣokùnkun, emi o fi kũkũ bò õrùn, òṣupa kì yio si fi imọlẹ rẹ̀ hàn.

8 Gbogbo imọlẹ oju ọrun li emi o mu ṣokùnkun lori rẹ, emi o gbe okùnkun kà ilẹ rẹ, li Oluwa Ọlọrun wi.

9 Emi o si bí ọ̀pọlọpọ enia ninu, nigbati emi o ba mu iparun rẹ wá sãrin awọn orilẹ-ède, si ilẹ ti iwọ kò ti mọ̀ ri.

10 Nitõtọ, emi o mu ki ẹnu yà ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède si ọ, awọn ọba wọn yio si bẹ̀ru gidigidi nitori rẹ, nigbati emi o ba mì idà mi niwaju wọn; nwọn o si warìri nigbagbogbo, olukuluku enia fun ẹmi ara rẹ̀, li ọjọ iṣubu rẹ.

11 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Idà ọba Babiloni yio wá sori rẹ.

12 Emi o mu ki ọ̀pọlọpọ enia rẹ ṣubu nipa idà awọn alagbara, ẹlẹ́rù awọn orilẹ-ẹ̀de ni gbogbo wọn; nwọn o si bà afẹ́ Egipti jẹ́, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ ni nwọn o parun.

13 Emi o si pa gbogbo awọn ẹranko inu rẹ̀ run kuro lẹba awọn omi nla, bẹ̃ni ẹsẹ enia kì yio rú wọn mọ́ lailai, tabi pátakò awọn ẹranko kì yio rú wọn.

14 Nigbana li emi o mu ki omi wọn ki o rẹlẹ, emi o si mu ki odò wọn ki o ṣàn bi oróro, li Oluwa Ọlọrun wi.

15 Nigbati emi o mu ki ilẹ Egipti di ahoro ti ilẹ na yio si di alaini ohun ti o kún inu rẹ̀ ri, nigbati emi o kọlù gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀, nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa.

16 Eyi ni ohùn-rére, nwọn o si pohùnrére rẹ̀: awọn ọmọbinrin awọn orilẹ-ède yio pohùnrére rẹ̀: nwọn o pohùnrére nitori rẹ̀, ani fun Egipti, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.

17 O si tun ṣe li ọdun kejila, li ọjọ kẹ̃dogun oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe.

18 Ọmọ enia, pohùnrére fun ọ̀pọlọpọ enia Egipti, ki o si sọ̀ wọn kalẹ, on, ati awọn ọmọbinrin orilẹ-ède olokiki, si ìsalẹ aiye, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ sinu ihò.

19 Tani iwọ julọ li ẹwà? sọkalẹ, ki a si tẹ́ ọ tì awọn alaikọla.

20 Nwọn o ṣubu li ãrin awọn ti a fi idà pa: a fi on le idà lọwọ: fà a, ati awọn ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀.

21 Awọn alagbara lãrin awọn alagbara yio sọ̀rọ si i lati ãrin ipò-okú wá, pẹlu awọn ti o ràn a lọwọ: nwọn sọkalẹ lọ, nwọn dubulẹ, awọn alaikọla ti a fi idà pa.

22 Assuru wà nibẹ̀ ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ wà lọdọ rẹ̀: gbogbo wọn li a pa, ti o ti ipa idà ṣubu:

23 Ibojì awọn ẹniti a gbe kà ẹgbẹ́ ihò, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ si yi ibojì rẹ̀ ka, gbogbo wọn li a pa, nwọn ti ipa idà ṣubu, ti o da ẹ̀ru silẹ ni ilẹ alãye.

24 Elamu wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ yi ibojì rẹ̀ ka, gbogbo wọn li a pa, nwọn ti ipa idà ṣubu, ti nwọn sọkalẹ li alaikọla si ìsalẹ aiye, ti o da ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye; sibẹ nwọn ti rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.

25 Nwọn ti gbe akete kan kalẹ fun u li ãrin awọn ti a pa pẹlu gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka, gbogbo wọn alaikọla ti a fi idà pa: bi a tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye, sibẹ nwọn ti rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: a fi i si ãrin awọn ti a pa.

26 Meṣeki ati Tubali wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka: gbogbo wọn alaikọlà ti a fi idà pa, bi nwọn tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye.

27 Nwọn kì yio si dubulẹ tì awọn alagbara ti o ṣubu ninu awọn alaikọlà, ti nwọn sọkalẹ lọ si ipò-okú pẹlu ihámọra ogun wọn: nwọn ti fi idà wọn rọ ori wọn, ṣugbọn aiṣedẽde wọn yio wà lori egungun wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ẹ̀ru awọn alagbara ni ilẹ alãye.

28 Lõtọ, a o fọ́ ọ lãrin awọn alaikọlà, iwọ o si dubulẹ tì awọn ti a fi idà pa.

29 Edomu wà nibẹ, awọn ọba rẹ̀, ati awọn ọmọ-alade rẹ̀, ti a tẹ́ pẹlu agbara wọn tì awọn ti a fi idà pa, nwọn o dubulẹ tì awọn alaikọlà, ati pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.

30 Awọn ọmọ-alade ariwa wà nibẹ, gbogbo wọn, ati awọn ara Sidoni, ti nwọn sọkalẹ lọ pẹlu awọn ti a pa; pẹlu ẹ̀ru wọn, oju agbara wọn tì wọn; nwọn si dubulẹ li alaikọlà pẹlu awọn ti a fi idà pa, nwọn si rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.

31 Farao yio ri wọn, a o si tù u ninu lori gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, ani Farao ati gbogbo ogun rẹ̀ ti a fi idà pa, li Oluwa Ọlọrun wi.

32 Nitoriti emi ti dá ẹ̀ru mi silẹ ni ilẹ alãye: a o si tẹ́ ẹ si ãrin awọn alaikọlà, pẹlu awọn ti a fi idà pa ani Farao ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.