Esek 36 YCE

1 ATI iwọ, ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn oke Israeli, si wipe, Ẹnyin oke Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa:

2 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Nitori ti ọta ti wi si nyin pe, Aha, ani ibi giga igbãni jẹ tiwa ni ini:

3 Nitorina sọtẹlẹ, ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, Nitõtọ nitori nwọn ti sọ ọ di ahoro, ti nwọn si gbe ọ mì niha gbogbo, ki ẹnyin ba le jẹ ini fun awọn keferi iyokù, ti a mu nyin si ẹnu, ti ẹnyin si jasi ẹ̀gan awọn enia:

4 Nitorina, ẹnyin oke Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun; Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oke-nla, ati fun awọn oke kékèké, fun awọn odò, ati fun awọn afonifoji, fun ibi idahoro, ati fun awọn ilu ti a kọ̀ silẹ, ti o di ijẹ ati iyọsùtisi fun awọn keferi iyokù ti o yika kiri;

5 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitõtọ ninu iná owu mi li emi ti sọ̀rọ si awọn keferi iyokù, ati si gbogbo Idumea, ti o ti fi ayọ̀ inu wọn gbogbo yàn ilẹ mi ni iní wọn, pẹlu àrankan inu, lati ta a nù fun ijẹ.

6 Nitorina sọtẹlẹ niti ilẹ Israeli, ki o si wi fun awọn oke nla, ati fun awọn oke kékèké, fun awọn odò, ati fun awọn afonifoji, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Wò o, emi ti sọ̀rọ ninu owu mi, ati ninu irúnu mi, nitori ti ẹnyin ti rù itiju awọn keferi.

7 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi ti gbe ọwọ́ mi soke, Nitõtọ awọn keferi ti o yi nyin ka, awọn ni yio rù itiju wọn.

8 Ṣugbọn ẹnyin, oke Israeli, ẹnyin o yọ ẹka jade, ẹ o si so eso nyin fun Israeli enia mi; nitori nwọn fẹrẹ̀ de.

9 Si kiyesi i, emi wà fun nyin, emi o si yipadà si nyin, a o si ro nyin, a o si gbìn nyin:

10 Emi o si mu enia bi si i lori nyin, gbogbo ile Israeli, ani gbogbo rẹ̀: awọn ilu yio si ni olugbe, a o si kọ́ ibi ti o di ahoro:

11 Emi o si mu enia ati ẹranko bi si i lori nyin; nwọn o si pọ̀ si i, nwọn o si rẹ̀: emi o si mu nyin joko ni ibugbe nyin, bi ti atijọ, emi o si ṣe si nyin jù igbà ibẹ̀rẹ nyin lọ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.

12 Nitõtọ, emi o mu ki enia rìn lori nyin, ani Israeli enia mi; nwọn o si ni ọ, iwọ o si jẹ iní wọn, iwọ kì yio si gbà wọn li ọmọ mọ lati isisiyi lọ.

13 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori nwọn wi fun nyin, pe, Iwọ jẹ enia run, o si ti gbà awọn orilẹ-ède li ọmọ;

14 Nitorina iwọ kì yio jẹ enia run mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio gbà awọn orilẹ rẹ li ọmọ mọ, li Oluwa Ọlọrun wi.

15 Bẹ̃ni emi kì yio mu ki enia gbọ́ ìtiju awọn keferi ninu rẹ mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio rù ẹ̀gan awọn orilẹ-ède mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio mu ki orilẹ-ẹ̀de rẹ ṣubu mọ, li Oluwa Ọlọrun wi.

16 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

17 Ọmọ enia, nigbati ile Israeli ngbe ilẹ ti wọn; nwọn bà a jẹ nipa ọ̀na wọn, ati nipa iṣe wọn: ọ̀na wọn loju mi dabi aimọ́ obinrin ti a mu kuro.

18 Nitorina emi fi irúnu mi si ori wọn, nitori ẹ̀jẹ ti wọn ti ta sori ilẹ na, ati nitori ere wọn ti wọn ti fi bà a jẹ.

19 Emi si ti tú wọn ká sãrin awọn keferi, a si fọn wọn ká si gbogbo ilẹ: emi dá wọn lẹjọ, gẹgẹ bi ọ̀na wọn, ati gẹgẹ bi iṣe wọn.

20 Nigbati awọn si wọ̀ inu awọn keferi, nibiti nwọn lọ, nwọn bà orukọ mimọ́ mi jẹ, nigbati nwọn wi fun wọn pe, Awọn wọnyi li enia Oluwa, nwọn si ti jade kuro ni ilẹ rẹ̀.

21 Ṣugbọn ãnu orukọ mimọ́ mi ṣe mi, ti ile Israeli ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti nwọn lọ.

22 Nitorina sọ fun ile Israeli, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ile Israeli, emi kò ṣe eyi nitori ti nyin, ṣugbọn fun orukọ mimọ́ mi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti ẹnyin lọ.

23 Emi o si sọ orukọ nla mi di mimọ́, ti a bajẹ lãrin awọn keferi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin wọn; awọn keferi yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati a o sọ mi di mimọ́ ninu nyin niwaju wọn, li Oluwa Ọlọrun wi.

24 Nitori emi o mu nyin kuro lãrin awọn keferi, emi o si ṣà nyin jọ kuro ni gbogbo ilẹ, emi o si mu nyin padà si ilẹ ti nyin.

25 Nigbana ni emi o fi omi mimọ́ wọ́n nyin, ẹnyin o si mọ́: emi o si wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin.

26 Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin.

27 Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, emi o si mu ki ẹ ma rìn ninu aṣẹ mi, ẹnyin o pa idajọ mi mọ, ẹ o si ma ṣe wọn.

28 Ẹnyin o si ma gbe ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin; ẹnyin o si ma jẹ enia mi, emi o si ma jẹ Ọlọrun nyin.

29 Emi o si gbà nyin là kuro ninu aimọ́ nyin gbogbo: emi o si pè ọkà wá, emi o si mu u pọ̀ si i, emi kì yio si mu ìyan wá ba nyin.

30 Emi o si sọ eso-igi di pupọ̀, ati ibísi oko, ki ẹ má bà gbà ẹ̀gan ìyan mọ lãrin awọn keferi.

31 Nigbana li ẹnyin o ranti ọ̀na buburu nyin, ati iṣe nyin ti kò dara, ẹ o si sú ara nyin li oju ara nyin fun aiṣedẽde nyin, ati fun irira nyin.

32 Kì iṣe nitori ti nyin li emi ṣe eyi, ni Oluwa Ọlọrun wi, ẹ mọ̀ eyi: ki oju ki o tì nyin, ki ẹ si dãmú nitori ọ̀na ara nyin, ile Israeli.

33 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Li ọjọ ti emi o ti wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu aiṣedẽde nyin gbogbo, emi o mu ki a tun gbe ilu, a o si kọ́ ibi ahoro wọnni.

34 Ilẹ ahoro li a o si ro, ti o ti di ahoro li oju gbogbo awọn ti o ti kọja.

35 Nwọn o si wipe, Ilẹ yi ti o ti di ahoro ti dabi ọgbà Edeni; ati ilu ti o tú, ti o di ahoro, ti o si parun, di ilu olodi, o si ni olugbe.

36 Nigbana ni awọn keferi iyokù yika nyin yio mọ̀ pe emi Oluwa ti kọ́ ilu ti o parun, emi si ti gbìn eyiti o ti di ahoro: emi Oluwa ti sọ ọ, emi o si ṣe e.

37 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ile Israeli yio bere eyi lọwọ mi, lati ṣe e fun wọn, emi o mu enia bi si i fun wọn bi ọwọ́-ẹran.

38 Gẹgẹ bi ọwọ́-ẹran mimọ́, bi ọwọ́-ẹran Jerusalemu ni àse wọn ti o ni ironu, bẹ̃ni ilu ti o di ahoro yio kún fun enia: nwọn o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.