Esek 19 YCE

1 PẸLUPẸLU iwọ pohùn-rére ẹkun fun awọn ọmọ-alade Israeli,

2 Si wipe, Kini iyá rẹ? Abo kiniun: o dubulẹ lãrin kiniun, o bọ́ awọn ọmọ rẹ lãrin ọmọ kiniun.

3 O si tọ́ ọkan ninu ọmọ rẹ̀ dàgba: o di ọmọ kiniun, o si kọ́ ati ṣọdẹ; o pa enia jẹ.

4 Awọn orilẹ-ède pẹlu gburo rẹ̀: a mu u ninu iho wọn, nwọn si fi ẹ̀wọn mu u lọ si ilẹ Egipti.

5 Nigbati o si ri pe on si duro, ti ireti rẹ̀ si sọnu, nigbana ni o mu omiran ninu ọmọ rẹ̀, o si sọ ọ di ọmọ kiniun.

6 On si lọ soke lọ sodo lãrin awọn kiniun, o di ọmọ kiniun, o si kọ́ lati ṣọdẹ, o si pa enia jẹ.

7 On si mọ̀ awọn opo wọn, o si sọ ilu-nla wọn di ahoro; ilẹ na di ahoro, ati ẹkún rẹ̀, pẹlu nipa ariwo kike ramuramu rẹ̀.

8 Nigbana ni awọn orilẹ-ède kó tì i nihà gbogbo lati ìgberiko wá, nwọn si na awọ̀n wọn le e lori: a mu u ninu iho wọn.

9 Nwọn si fi i sinu ẹṣọ́ ninu ẹ̀wọn, nwọn si mu u wá sọdọ ọba Babiloni: nwọn mu u lọ sinu ilu olodi, ki a má ba gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ lori oke Israeli.

10 Iyá rẹ dabi àjara kan ninu ẹjẹ rẹ, ti a gbìn si eti odò, on kún fun eso, o si kún fun ẹka nitori ọ̀pọlọpọ odò.

11 O si ni ọpá ti o le fun ọpá-ade awọn ti o jẹ oye; giga rẹ̀ li a gbega lãrin ẹka gigun, o si farahàn ninu giga rẹ̀ pẹlu ọ̀pọlọpọ ẹka rẹ̀.

12 Ṣugbọn a fã a tu ni irúnu, a wọ ọ lulẹ, ẹfũfu ila-õrun si gbe eso rẹ̀, ọpá lile rẹ̀ ti ṣẹ, o si rọ; iná jo o run.

13 Nisisiyi a si gbìn i si aginju, ni ilẹ gbigbẹ ati ilẹ ongbẹ.

14 Iná si jade lati inu ọpá kan ninu ẹka rẹ̀, ti o ti jo eso rẹ̀ run, tobẹ̃ ti kò fi ni ẹka ti o le lati ṣe ọpa lati joye. Eyi ni ohùnrére ẹkun, yio si jẹ ohùn-rére ẹkun.