1 LI ọdun kẹta Kirusi, ọba Persia, li a fi ọ̀rọ kan hàn fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari; otitọ li ọ̀rọ na, ati lãla na tobi, o si mọ̀ ọ̀rọ na, o si moye iran na.
2 Li ọjọ wọnni li emi Danieli fi ikãnu ṣọ̀fọ li ọ̀sẹ mẹta gbako.
3 Emi kò jẹ onjẹ ti o dara, bẹ̃ni kò si si ẹran tabi ọti-waini ti o wá si ẹnu mi, bẹ̃li emi kò fi ororo kùn ara mi rara, titi ọ̀sẹ mẹta na fi pe.
4 Nigbati o di ọjọ kẹrinlelogun oṣu kini, bi mo ti wà li eti odò nla, ti ijẹ Hiddekeli;
5 Nigbana ni mo gbé oju mi soke, mo wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti o wọ̀ aṣọ àla, ẹ̀gbẹ ẹniti a fi wura Ufasi daradara dì li àmure:
6 Ara rẹ̀ pẹlu dabi okuta berili, oju rẹ̀ si dabi manamána, ẹyinju rẹ̀ dabi iná fitila, apa ati ẹsẹ rẹ̀ li awọ̀ ti o dabi idẹ ti a wẹ̀ dan, ohùn ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ si dabi ohùn ijọ enia pupọ.