15 Nigbati o si ti sọ iru ọ̀rọ bayi fun mi tan, mo dojukọ ilẹ mo si yadi.
16 Si wò o, ẹnikan ti jijọ rẹ̀ dabi ti awọn ọmọ enia fi ọwọ kan ète mi: nigbana ni mo ya ẹnu mi, mo si fọhùn, mo si wi fun ẹniti o duro tì mi pe, oluwa mi, niti iran na, irora mi pada sinu mi, emi kò si lagbara mọ.
17 Nitoripé bawo ni ọmọ-ọdọ oluwa mi yi yio ti ṣe le ba oluwa mi yi sọ̀rọ? ṣugbọn bi o ṣe temi ni, lojukanna, agbara kò kù ninu mi, bẹ̃ni kò si kù ẽmi ninu mi.
18 Nigbana ni ẹnikan ti o ni aworan enia wá o si tun fi ọwọ tọ́ mi, o si mu mi lara le,
19 O si wipe, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, má bẹ̀ru: alafia ni fun ọ, mu ara le. Ani mu ara le, Nigbati on ba mi sọ̀rọ, a si mu mi lara le, mo si wipe, Ki oluwa mi ki o ma sọ̀rọ, nitoriti iwọ ti mu mi lara le.
20 Nigbana ni o wipe, Iwọ, ha mọ̀ idi ohun ti mo tọ̀ ọ wá si? nisisiyi li emi o si yipada lọ iba balogun Persia jà: nigbati emi ba si jade lọ, kiyesi i, balogun Hellene yio wá.
21 Ṣugbọn emi o fi eyi ti a kọ sinu iwe otitọ hàn ọ: kò si si ẹniti o ràn mi lọwọ si awọn wọnyi, bikoṣe Mikaeli balogun nyin.