5 Nigbana ni mo gbé oju mi soke, mo wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti o wọ̀ aṣọ àla, ẹ̀gbẹ ẹniti a fi wura Ufasi daradara dì li àmure:
6 Ara rẹ̀ pẹlu dabi okuta berili, oju rẹ̀ si dabi manamána, ẹyinju rẹ̀ dabi iná fitila, apa ati ẹsẹ rẹ̀ li awọ̀ ti o dabi idẹ ti a wẹ̀ dan, ohùn ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ si dabi ohùn ijọ enia pupọ.
7 Emi Danieli nikanṣoṣo li o si ri iran na, awọn ọkunrin ti o si wà pẹlu mi kò ri iran na; ṣugbọn ìwariri nlanla dà bò wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi sá lọ lati fi ara wọn pamọ́.
8 Nitorina emi nikan li o kù, ti mo si ri iran nla yi, kò si kù agbara ninu mi: ẹwà mi si yipada lara mi di ibajẹ, emi kò si lagbara mọ.
9 Sibẹ mo gbọ́ ohùn ọ̀rọ rẹ̀: nigbati mo si gbọ́ ohùn ọ̀rọ rẹ̀, nigbana ni mo dãmu, mo si wà ni idojubolẹ̀.
10 Sa si kiyesi i, ọwọ kan kàn mi, ti o gbé mi dide lori ẽkun mi, ati lori atẹlẹwọ mi.
11 O si wi fun mi pe, Danieli, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, ki oye ọ̀rọ ti mo nsọ fun ọ ki o ye ọ, ki o si duro ni ipò rẹ: nitoripe iwọ li a rán mi si nisisiyi. Nigbati on ti sọ̀rọ bayi fun mi, mo dide duro ni ìwariri.