1 PẸLUPẸLU li ọdun kini Dariusi ara Media, emi pãpa duro lati mu u lọkàn le, ati lati fi idi rẹ̀ kalẹ.
2 Njẹ nisisiyi li emi o fi otitọ hàn ọ, Kiyesi i, ọba mẹta pẹlu ni yio dide ni Persia; ẹkẹrin yio si ṣe ọlọrọ̀ jù gbogbo wọn lọ: ati nipa agbara rẹ̀ ni yio fi fi ọrọ̀ rú gbogbo wọn soke si ijọba Hellene.
3 Ọba alagbara kan yio si dide, yio si fi agbara nla ṣe akoso, yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀.
4 Nigbati on ba dide tan, ijọba rẹ̀ yio fọ́, a o si pin i si orígun mẹrẹrin ọrun; kì si iṣe fun ọmọ rẹ̀, pẹlupẹlu kì si iṣe ninu agbara rẹ̀ ti on fi jọba, nitoriti a o fa ijọba rẹ̀ tu, ani fun ẹlomiran lẹhin awọn wọnyi.
5 Ọba iha gusu yio si lagbara; ṣugbọn ọkan ninu awọn balogun rẹ̀, on o si lagbara jù u lọ, yio si jọba, ijọba rẹ̀ yio jẹ ijọba nla.