10 Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ̀ yio ru soke, nwọn o si gbá ogun nla ọ̀pọlọpọ enia jọ; ẹnikan yio wọle wá, yio si bolẹ̀, yio si kọja lọ. Nigbana ni yio pada yio si gbé ogun lọ si ilu olodi rẹ̀.
11 Ọba gusu yio si fi ibinu ru soke, yio si jade wá ba a jà, ani, ọba ariwa na: on o si kó enia pipọ jọ; ṣugbọn a o fi ọ̀pọlọpọ na le e lọwọ.
12 Yio si kó ọ̀pọlọpọ na lọ, ọkàn rẹ̀ yio si gbé soke; on o si bì ọ̀pọlọpọ ẹgbãrun enia ṣubu; ṣugbọn a kì yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ nipa eyi.
13 Nitoripe ọba ariwa yio si yipada, yio si kó ọ̀pọlọpọ enia jọ ti yio pọ̀ jù ti iṣaju lọ, yio si wá lẹhin ọdun melokan pẹlu ogun nla, ati ọ̀pọlọpọ ọrọ̀.
14 Li akoko wọnni li ọ̀pọlọpọ yio si dide si ọba gusu; awọn ọlọ̀tẹ ninu awọn enia rẹ̀ yio si gbé ara wọn ga lati fi ẹsẹ iran na mulẹ pẹlu: ṣugbọn nwọn o ṣubu.
15 Bẹ̃li ọba ariwa yio si wá, yio si mọdi, yio si gbà ilu olodi; apá ogun ọba gusu kì yio le duro, ati awọn ayanfẹ enia rẹ̀, bẹ̃ni kì yio si agbara lati da a duro.
16 Ṣugbọn ẹniti o tọ̀ ọ wá yio mã ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu ara rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio duro niwaju rẹ̀; on o si duro ni ilẹ daradara nì, ti yio si fi ọwọ rẹ̀ parun.