20 Nigbana ni ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀ ti yio mu agbowode kan rekọja ninu ogo ijọba (ilẹ Juda): ṣugbọn niwọn ijọ melokan li a o si pa a run, kì yio ṣe nipa ibinu tabi loju ogun.
21 Ni ipò rẹ̀ li enia lasan kan yio dide, ẹniti nwọn kì yio fi ọlá ọba fun: ṣugbọn yio wá lojiji, yio si fi arekereke gbà ijọba.
22 Ogun ti mbò ni mọlẹ li a o fi bò wọn mọlẹ niwaju rẹ̀, a o si fọ ọ tũtu, ati pẹlu ọmọ-alade majẹmu kan.
23 Ati lẹhin igbati a ba ti ba a ṣe ipinnu tan, yio fi ẹ̀tan ṣiṣẹ: yio si gòke lọ, yio si fi enia diẹ bori.
24 Yio si wọ̀ gbogbo ibi igberiko ọlọra; yio si ṣe ohun ti awọn baba rẹ̀ kò ṣe ri, tabi awọn baba nla rẹ̀; yio si fọn ikogun, ìfa, ati ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ ká si ãrin wọn: yio si gbèro tẹlẹ si ilu olodi, ani titi akokò kan.
25 Yio si rú agbara ati igboya rẹ̀ soke si ọba gusu ti on ti ogun nla; a o si rú ọba gusu soke si ija pẹlu ogun nlanla ati alagbara pupọ; ṣugbọn on kì yio le duro: nitori nwọn o gba èro tẹlẹ si i.
26 Awọn ẹniti o jẹ ninu adidùn rẹ̀ ni yio si pa a run, ogun rẹ̀ yio si tàn kalẹ; ọ̀pọlọpọ ni yio si ṣubu ni pipa.