25 Yio si rú agbara ati igboya rẹ̀ soke si ọba gusu ti on ti ogun nla; a o si rú ọba gusu soke si ija pẹlu ogun nlanla ati alagbara pupọ; ṣugbọn on kì yio le duro: nitori nwọn o gba èro tẹlẹ si i.
26 Awọn ẹniti o jẹ ninu adidùn rẹ̀ ni yio si pa a run, ogun rẹ̀ yio si tàn kalẹ; ọ̀pọlọpọ ni yio si ṣubu ni pipa.
27 Ọkàn awọn ọba mejeji wọnyi ni yio wà lati ṣe buburu, nwọn o si mã sọ̀rọ eké lori tabili kan, ṣugbọn kì yio jẹ rere; nitoripe opin yio wà li akokò ti a pinnu.
28 Nigbana ni yio pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀ ti on ti ọrọ̀ pupọ: ọkàn rẹ̀ yio si lodi si majẹmu mimọ́ nì, yio ṣe e, yio si pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀.
29 Yio si pada wá li akokò ti a pinnu, yio si wá si iha gusu; ṣugbọn kì yio ri bi ti iṣaju, ni ikẹhin.
30 Nitoripe ọkọ̀ awọn ara Kittimu yio tọ̀ ọ wá, nitorina ni yio ṣe dãmu, yio si yipada, yio si ni ibinu si majẹmu mimọ́ nì; bẹ̃ni yio ṣe; ani on o yipada, yio si tun ni idapọ pẹlu awọn ti o kọ̀ majẹmu mimọ́ na silẹ.
31 Agbara ogun yio si duro li apa tirẹ̀, nwọn o si sọ ibi mimọ́, ani ilu olodi na di aimọ́, nwọn o si mu ẹbọ ojojumọ kuro, nwọn o si gbé irira isọdahoro nì kalẹ.