37 Bẹ̃li on kì yio si kà Ọlọrun awọn baba rẹ̀ si, tabi ifẹ awọn obinrin, on kì yio si kà ọlọrun kan si: nitoriti yio gbé ara rẹ̀ ga jù ẹni gbogbo lọ.
38 Ṣugbọn ni ipò rẹ̀, yio ma bu ọlá fun ọlọrun awọn ilu olodi, ani ọlọrun kan ti awọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ri ni yio ma fi wura, ati fadaka, ati okuta iyebiye, ati ohun daradara bu ọlá fun.
39 Bẹ̃ gẹgẹ ni yio ṣe ninu ilu olodi wọnni ti o lagbara julọ nipa iranlọwọ ọlọrun ajeji, ẹniti o jẹ́wọ rẹ̀ ni yio fi ogo fun, ti yio si mu ṣe alakoso ọ̀pọlọpọ, yio si pín ilẹ fun li ère.
40 Li akokò opin, ọba gusu yio kàn a, ọba ariwa yio si fi kẹkẹ́, ati ẹlẹṣin, ati ọ̀pọlọpọ ọkọ̀, kọ lu u bi afẹyika-ìji: on o si wọ̀ ilẹ wọnni yio si bò wọn mọlẹ, yio si rekọja.
41 Yio si wọ̀ ilẹ ologo nì pẹlu, ọ̀pọlọpọ li a o si bì ṣubu: ṣugbọn awọn wọnyi ni yio si bọ lọwọ rẹ̀, ani Edomu, ati Moabu, ati olori awọn ọmọ Ammoni.
42 On o si nà ọwọ rẹ̀ jade si ilẹ wọnni pẹlu, ilẹ Egipti kì yio si là a.
43 Ṣugbọn on o lagbara lori iṣura wura, ati ti fadaka, ati lori gbogbo ohun daradara ni ilẹ Egipti: ati awọn ara Libia, awọn ara Etiopia yio si wà lẹhin rẹ̀.