40 Li akokò opin, ọba gusu yio kàn a, ọba ariwa yio si fi kẹkẹ́, ati ẹlẹṣin, ati ọ̀pọlọpọ ọkọ̀, kọ lu u bi afẹyika-ìji: on o si wọ̀ ilẹ wọnni yio si bò wọn mọlẹ, yio si rekọja.
41 Yio si wọ̀ ilẹ ologo nì pẹlu, ọ̀pọlọpọ li a o si bì ṣubu: ṣugbọn awọn wọnyi ni yio si bọ lọwọ rẹ̀, ani Edomu, ati Moabu, ati olori awọn ọmọ Ammoni.
42 On o si nà ọwọ rẹ̀ jade si ilẹ wọnni pẹlu, ilẹ Egipti kì yio si là a.
43 Ṣugbọn on o lagbara lori iṣura wura, ati ti fadaka, ati lori gbogbo ohun daradara ni ilẹ Egipti: ati awọn ara Libia, awọn ara Etiopia yio si wà lẹhin rẹ̀.
44 Ṣugbọn ìhin lati ila-õrùn, ati lati iwọ-õrùn wá yio dãmu rẹ̀: nitorina ni yio ṣe fi ìbinu nla jade lọ lati ma parun, ati lati mu ọ̀pọlọpọ kuro patapata.
45 On o si pagọ ãfin rẹ̀ lãrin omi kọju si òke mimọ́ ologo nì; ṣugbọn on o si de opin rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio ràn a lọwọ.