6 Lẹhin ọdun pipọ nwọn o si kó ara wọn jọ pọ̀; ọmọbinrin ọba gusu yio wá sọdọ ọba ariwa, lati ba a dá majẹmu: ṣugbọn on kì yio le di agbara apá na mu; bẹ̃ni on kì yio le duro, tabi apá rẹ̀: ṣugbọn a o fi on silẹ, ati awọn ti o mu u wá, ati ẹni ti o bi i, ati ẹniti nmu u lọkàn le li akokò ti o kọja.
7 Ṣugbọn ninu ẹka gbòngbo rẹ̀ li ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀, ẹniti yio wá pẹlu ogun, yio si wọ̀ ilu-olodi ọba ariwa, yio si ba wọn ṣe, yio si bori.
8 On o si kó oriṣa wọn pẹlu ere didà wọn, ati ohunelo wọn daradara, ti fadaka, ati ti wura ni igbekun lọ si Egipti; on o si duro li ọdun melokan kuro lọdọ ọba ariwa.
9 On o si lọ si ijọba ọba gusu, ṣugbọn yio yipada si ilẹ ontikararẹ̀.
10 Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ̀ yio ru soke, nwọn o si gbá ogun nla ọ̀pọlọpọ enia jọ; ẹnikan yio wọle wá, yio si bolẹ̀, yio si kọja lọ. Nigbana ni yio pada yio si gbé ogun lọ si ilu olodi rẹ̀.
11 Ọba gusu yio si fi ibinu ru soke, yio si jade wá ba a jà, ani, ọba ariwa na: on o si kó enia pipọ jọ; ṣugbọn a o fi ọ̀pọlọpọ na le e lọwọ.
12 Yio si kó ọ̀pọlọpọ na lọ, ọkàn rẹ̀ yio si gbé soke; on o si bì ọ̀pọlọpọ ẹgbãrun enia ṣubu; ṣugbọn a kì yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ nipa eyi.