16 Nigbana ni Danieli wọle lọ, o si bère lọwọ ọba pe, ki o fi akokò fun on, o si wipe, on o fi itumọ rẹ̀ hàn fun ọba.
17 Nigbana ni Danieli lọ si ile rẹ̀, o si fi nkan na hàn fun Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
18 Pe, ki nwọn ki o bère ãnu lọwọ Ọlọrun, Oluwa ọrun, nitori aṣiri yi: ki Danieli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ má ba ṣegbe pẹlu awọn ọlọgbọ́n Babeli iyokù, ti o wà ni Babeli.
19 Nigbana ni a fi aṣiri na hàn fun Danieli ni iran li oru, Danieli si fi ibukún fun Ọlọrun, Oluwa ọrun.
20 Danieli dahùn o si wipe, Olubukún ni orukọ Ọlọrun titi lai; nitori tirẹ̀ li ọgbọ́n ati agbara.
21 O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye:
22 O fi ohun ijinlẹ ati aṣiri hàn: o mọ̀ ohun ti o wà li òkunkun, lọdọ rẹ̀ ni imọlẹ si wà.