3 Ọba si wi fun wọn pe, mo lá alá kan, ọkàn mi kò si le ilẹ lati mọ̀ alá na.
4 Nigbana ni awọn Kaldea wi fun ọba li ede awọn ara Siria pe, Ki ọba ki o pẹ́: rọ́ alá na fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ, awa o si fi itumọ̀ na hàn.
5 Ọba dahùn o si wi fun awọn Kaldea pe, ohun na ti kuro li ori mi: bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, a o ké nyin wẹwẹ, a o si sọ ile nyin di ãtàn.
6 Ṣugbọn bi ẹnyin ba fi alá na hàn, ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, ẹnyin o gba ẹ̀bun ati ọrẹ ati ọlá nla li ọwọ mi: nitorina, ẹ fi alá na hàn fun mi, ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu.
7 Nwọn tun dahùn nwọn si wipe, Ki ọba ki o rọ alá na fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, awa o si fi itumọ̀ rẹ̀ hàn.
8 Ọba si dahùn o wi pe, emi mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin fẹ mu akoko pẹ, nitoriti ẹnyin ri pe nkan na lọ li ori mi.
9 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi, njẹ ipinnu kan li ẹnyin ti ṣe: nitoriti ẹnyin mura lati ma sọ̀rọ eke ati idibajẹ niwaju mi, titi akoko yio fi kọja: nitorina ẹ rọ́ alá na fun mi emi o si mọ̀ pe ẹnyin o le fi itumọ̀ rẹ̀ hàn fun mi pẹlu.