30 Ọba si dahùn, o wipe, Ko ṣepe eyi ni Babeli nla, ti emi ti fi lile agbara mi kọ́ ni ile ijọba, ati fun ogo ọlanla mi?
31 Bi ọ̀rọ na si ti wà lẹnu ọba, ohùn kan fọ̀ lati ọrun wá, pe, Nebukadnessari, ọba, iwọ li a sọ fun; pe, a gba ijọba kuro lọwọ rẹ.
32 A o si le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ: nwọn o si mu ọ jẹ koriko bi malu, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe, Ọga-ogo ni iṣe olori ninu ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.
33 Ni wakati kanna ni nkan na si ṣẹ si Nebukadnessari, a si le e kuro larin enia, o si jẹ koriko bi malu, a si mu ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, titi irun ori rẹ̀ fi kún gẹgẹ bi iyẹ idì, ẽkana rẹ̀ si dabi ti ẹiyẹ.
34 Li opin igba na, Emi Nebukadnessari si gbé oju mi soke si ọrun, oye mi si pada tọ̀ mi wá, emi si fi ibukún fun Ọga-ogo, mo yìn, mo si fi ọla fun ẹniti o wà titi lailai, ẹniti agbara ijọba rẹ̀ jẹ ijọba ainipẹkun, agbara ati ijọba rẹ̀ lati irandiran.
35 Gbogbo awọn araiye li a si kà si bi ohun asan, on a si ma ṣe gẹgẹ bi o ti wù u ninu ogun ọrun, ati larin awọn araiye: kò si si ẹniti idá ọwọ rẹ̀ duro, tabi ẹniti iwi fun u pe, Kini iwọ nṣe nì?
36 Lakoko kanna oye mi pada tọ̀ mi wá; ati niti ogo ijọba mi, ọlá ati ogo didan mi si pada wá sọdọ mi: awọn ìgbimọ ati awọn ijoye mi si ṣafẹri mi; a si fi ẹsẹ mi mulẹ ninu ijọba mi, emi si ni ọlanla agbara jù ti iṣaju lọ.