34 Li opin igba na, Emi Nebukadnessari si gbé oju mi soke si ọrun, oye mi si pada tọ̀ mi wá, emi si fi ibukún fun Ọga-ogo, mo yìn, mo si fi ọla fun ẹniti o wà titi lailai, ẹniti agbara ijọba rẹ̀ jẹ ijọba ainipẹkun, agbara ati ijọba rẹ̀ lati irandiran.
35 Gbogbo awọn araiye li a si kà si bi ohun asan, on a si ma ṣe gẹgẹ bi o ti wù u ninu ogun ọrun, ati larin awọn araiye: kò si si ẹniti idá ọwọ rẹ̀ duro, tabi ẹniti iwi fun u pe, Kini iwọ nṣe nì?
36 Lakoko kanna oye mi pada tọ̀ mi wá; ati niti ogo ijọba mi, ọlá ati ogo didan mi si pada wá sọdọ mi: awọn ìgbimọ ati awọn ijoye mi si ṣafẹri mi; a si fi ẹsẹ mi mulẹ ninu ijọba mi, emi si ni ọlanla agbara jù ti iṣaju lọ.
37 Nisisiyi, emi Nebukadnessari yìn, mo si gbé Ọba ọrun ga, mo si fi ọlá fun u, ẹniti gbogbo iṣẹ rẹ̀ iṣe otitọ, ati gbogbo ọ̀na rẹ̀ iṣe idajọ: ati awọn ti nrìn ninu igberaga, on le rẹ̀ wọn silẹ.