4 Nwọn nmu ọti-waini, nwọn si nkọrin ìyin si awọn oriṣa wura, ati ti fadaka, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta.
5 Ni wakati kanna ni awọn ika ọwọ enia kan jade wá, a si kọwe sara ẹfun ogiri niwaju ọpa-fitila li ãfin ọba: ọba si ri ọwọ ti o kọwe na.
6 Nigbana ni oju ọba yipada, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀, tobẹ̃ ti amure ẹ̀gbẹ rẹ̀ tu, ẽkunsẹ̀ rẹ̀ mejeji si nlù ara wọn.
7 Ọba si kigbe kikan pe, ki a mu awọn amoye, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá. Ọba dahùn o si wi fun awọn ọlọgbọ́n Babeli, pe, Ẹnikan ti o ba kà iwe yi, ti o ba si fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, on li a o fi aṣọ ododó wọ̀, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ̀ ọ li ọrùn, on o si jẹ ẹkẹta olori ni ijọba.
8 Nigbana ni gbogbo awọn amoye ọba wọle; ṣugbọn nwọn kò le kà iwe na, nwọn kò si le fi itumọ rẹ̀ hàn fun ọba.
9 Nigbana ni ẹ̀ru nla ba Belṣassari ọba gidigidi, oju rẹ̀ si yipada lori rẹ̀, ẹ̀ru si ba awọn ijoye rẹ̀.
10 Nitorina ni ayaba ṣe wọ ile-àse wá, nitori ọ̀ran ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; ayaba dahùn o si wipe, Ki ọba ki o pẹ́: má ṣe jẹ ki ìro-inu rẹ ki o dãmu rẹ, má si jẹ ki oju rẹ ki o yipada.