Dan 5:9-15 YCE

9 Nigbana ni ẹ̀ru nla ba Belṣassari ọba gidigidi, oju rẹ̀ si yipada lori rẹ̀, ẹ̀ru si ba awọn ijoye rẹ̀.

10 Nitorina ni ayaba ṣe wọ ile-àse wá, nitori ọ̀ran ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; ayaba dahùn o si wipe, Ki ọba ki o pẹ́: má ṣe jẹ ki ìro-inu rẹ ki o dãmu rẹ, má si jẹ ki oju rẹ ki o yipada.

11 Ọkunrin kan mbẹ ni ijọba rẹ, lara ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà; ati li ọjọ baba rẹ, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun lara rẹ̀: ẹniti Nebukadnessari ọba, baba rẹ, ani ọba, baba rẹ fi ṣe olori awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ti awọn alafọṣẹ:

12 Niwọnbi ẹmi titayọ ati ìmọ, ati oye itumọ alá, oye ati já alọ́, ati lati ma ṣe itumọ ọ̀rọ ti o diju, gbogbo wọnyi li a ri lara Danieli na, ẹniti ọba fi orukọ Belteṣassari fun, njẹ nisisiyi jẹ ki a pè Danieli wá, on o si fi itumọ rẹ̀ hàn.

13 Nigbana ni a mu Danieli wá siwaju ọba. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Iwọ ni Danieli nì, ti iṣe ti inu awọn ọmọ igbekun Juda! awọn ẹniti ọba, baba mi kó lati ilẹ Juda wá?

14 Emi ti gburo rẹ pe ẹmi Ọlọrun mbẹ lara rẹ, ati pe, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n titayọ lara rẹ,

15 Njẹ nisisiyi, a ti mu awọn amoye, ati awọn ọlọgbọ́n wá siwaju mi, ki nwọn ki o le ka iwe yi, ati lati fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn nwọn kò le fi itumọ ọ̀ran na hàn: