23 Nigbana ni ọba yọ̀ gidigidi, o si paṣẹ pe, ki nwọn ki o fà Danieli jade kuro ninu iho. Bẹ̃li a si fa Danieli jade kuro ninu iho, a kò si ri ipalara lara rẹ̀, nitoriti o gbà Ọlọrun rẹ̀ gbọ́.
24 Ọba si paṣẹ, pe ki a mu awọn ọkunrin wọnni wá, ti o fi Danieli sùn, nwọn si gbé wọn sọ sinu iho kiniun, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn aya wọn. Ki nwọn ki o to de isalẹ iho, awọn kiniun bori wọn, nwọn si fọ egungun wọn tũtu.
25 Nigbana ni Dariusi, ọba kọwe si gbogbo enia, orilẹ, ati ède ti o wà ni gbogbo aiye pe, Ki alafia ki o ma bi si i fun nyin.
26 Mo paṣẹ pe, Ni gbogbo igberiko ijọba mi, ki awọn enia ki o ma warìri, ki nwọn si ma bẹ̀ru niwaju Ọlọrun Danieli, nitoripe on li Ọlọrun alãye, on si duro lailai, ati ijọba rẹ̀, eyi ti a kì yio le parun ni, ati agbara ijọba rẹ̀ yio si wà titi de opin.
27 O ngbà ni, o si nyọ ni, o si nṣe iṣẹ-ami ati iṣẹ-iyanu li ọrun ati li aiye, ẹniti o gbà Danieli là lọwọ awọn kiniun.
28 Bẹ̃ni Danieli yi si nṣe rere ni igba ijọba Dariusi, ati ni igba ijọba Kirusi, ara Persia.