1 LI ọdun kini Belṣassari, ọba Babeli, ni Danieli lá alá, ati iran ori rẹ̀ lori akete rẹ̀: nigbana ni o kọwe alá na, o si sọ gbogbo ọ̀rọ na.
2 Danieli dahùn, o si wipe, Mo ri ni iran mi li oru, si kiyesi i, afẹfẹ mẹrẹrin ọrun njà loju okun nla.
3 Ẹranko mẹrin nla si ti inu okun jade soke, nwọn si yatọ si ara wọn.
4 Ẹranko kini dabi kiniun, o si ni iyẹ-apa idì: mo si wò titi a fi fà iyẹ-apa rẹ̀ wọnni tu, a si gbé e soke kuro ni ilẹ, a mu ki o fi ẹsẹ duro bi enia, a si fi aiya enia fun u.
5 Sa si kiyesi, ẹranko miran, ekeji, ti o dabi ẹranko beari, o si gbé ara rẹ̀ soke li apakan, o si ni egungun-ìha mẹta lẹnu rẹ̀ larin ehin rẹ̀: nwọn si wi fun u bayi pe, Dide ki o si jẹ ẹran pipọ.
6 Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u.