21 Mo ri iwo kanna si mba awọn enia-mimọ́ jagun, o si bori wọn.
22 Titi Ẹni-àgba ọjọ nì fi de, ti a si fi idalare fun awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo; titi akokò si fi de ti awọn enia-mimọ́ jogun ijọba na.
23 Bẹ̃li o wipe, Ẹranko kẹrin nì yio ṣe ijọba kẹrin li aiye, eyiti yio yàtọ si gbogbo ijọba miran, yio pa gbogbo aiye rẹ́, yio si tẹ̀ ẹ molẹ, yio si fọ ọ tũtu.
24 Ati iwo mẹwa, lati inu ijọba na wá ni ọba mẹwa yio dide: omiran kan yio si dide lẹhin wọn, on o si yàtọ si gbogbo awọn ti iṣaju, on o si bori ọba mẹta.
25 On o si ma sọ̀rọ nla si Ọga-ogo, yio si da awọn enia-mimọ́ ti Ọga-ogo lagara, yio si rò lati yi akokò ati ofin pada; a o si fi wọn le e lọwọ titi fi di igba akokò kan, ati awọn akokò, ati idaji akokò.
26 Ṣugbọn awọn onidajọ yio joko, nwọn o si gbà agbara ijọba rẹ̀ lọwọ rẹ̀ lati fi ṣòfo, ati lati pa a run de opin.
27 Ati ijọba, ati agbara ijọba ati ipa gbogbo ijọba ni gbogbo abẹ-ọrun, li a o si fi fun enia awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo, ijọba ẹniti iṣe ijọba ainipẹkun, ati gbogbo awọn alakoso ni yio ma sìn, ti nwọn o si ma tẹriba fun u.