4 Mo si ri àgbo na o nkàn siha iwọ-õrùn, ati si ariwa, ati si gusu; tobẹ ti gbogbo ẹranko kò fi le duro niwaju rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹniti o le gbani lọwọ rẹ̀: ṣugbọn o nṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀, o si nṣe ohun nlanla.
5 Bi mo si ti nwoye, kiyesi i, obukọ kan ti iha iwọ-õrùn jade wá sori gbogbo aiye, kò si fi ẹsẹ kan ilẹ: obukọ na si ni iwo nla kan lãrin oju rẹ̀.
6 O si tọ̀ àgbo ti o ni iwo meji na wá, eyi ti mo ti ri ti o duro lẹba odò na, o si fi irunu agbara sare si i.
7 Mo si ri i, o sunmọ ọdọ́-àgbo na, o si fi ikoro ibinu sare si i, o lu àgbo na bolẹ, o si ṣẹ́ iwo rẹ̀ mejeji: kò si si agbara ninu àgbo na, lati duro niwaju rẹ̀, ṣugbọn o lù u bolẹ o si tẹ̀ ẹ mọlẹ: kò si si ẹniti o le gbà àgbo na lọwọ rẹ̀.
8 Nigbana ni obukọ na nṣe ohun nla pupọpupọ, nigbati o si di alagbara tan, iwo nla na ṣẹ́; ati nipò rẹ̀ iwo mẹrin miran ti iṣe afiyesi si yọ jade si ọ̀na afẹfẹ mẹrẹrin ọrun.
9 Ati lati inu ọkan ninu wọn ni iwo kekere kan ti jade, ti o si di alagbara gidigidi, si iha gusu, ati si iha ila-õrùn, ati si iha ilẹ ogo.
10 O si di alagbara, titi de ogun ọrun, o si bì ṣubu ninu awọn ogun ọrun, ati ninu awọn irawọ si ilẹ, o si tẹ̀ wọn mọlẹ.