16 Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo ododo rẹ, lõtọ, jẹ ki ibinu ati irunu rẹ yi kuro lori Jerusalemu, ilu rẹ, òke mimọ́ rẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wa, ati ẹ̀ṣẹ awọn baba wa ni Jerusalemu, ati awọn enia rẹ fi di ẹ̀gan si gbogbo awọn ti o yi wa ka.
17 Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, gbọ́ adura ọmọ-ọdọ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, ki o si mu ki oju rẹ ki o mọlẹ si ibi-mimọ́ rẹ ti o dahoro, nitori ti Oluwa.
18 Tẹ eti rẹ silẹ, Ọlọrun mi, ki o si gbọ́: ṣi oju rẹ, ki o si wò idahoro wa, ati ilu ti a nfi orukọ rẹ pè: nitoriti awa kò gbé ẹ̀bẹ wa kalẹ niwaju rẹ nitori ododo wa, ṣugbọn nitori ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ nla.
19 Oluwa, gbọ́, Oluwa, dariji: Oluwa, tẹ eti rẹ silẹ ki o si ṣe; máṣe jafara, nitori ti iwọ tikararẹ, Ọlọrun mi: nitori orukọ rẹ li a fi npè ilu rẹ, ati awọn enia rẹ.
20 Bi emi si ti nwi, ti emi ngbadura, ati bi emi si ti njẹwọ ẹṣẹ mi, ati ẹ̀ṣẹ Israeli awọn enia mi, ti emi si ngbé ẹbẹ mi kalẹ niwaju Oluwa, Ọlọrun mi, nitori òke mimọ́ Ọlọrun mi.
21 Bẹni, bi mo ti nwi lọwọ ninu adura mi, ọkunrin na, Gabrieli ti mo ti ri ni iran mi li atetekọṣe, li a mu lati fò wá kankan, o de ọdọ mi niwọn akokò ẹbọ aṣãlẹ.
22 O mu mi mọ̀, o si mba mi sọ̀rọ wipe, Danieli, mo jade wá nisisiyi lati fi oye fun ọ.