2 Awọn ọmọ iyebiye Sioni, ti o niye lori bi wura didara, bawo li a ṣe kà wọn si bi ikoko amọ̀, iṣẹ ọwọ alamọ̀!
3 Ani ọ̀wawa nfà ọmu jade, nwọn nfi ọmu fun awọn ọmọ wọn: ṣugbọn ọmọbinrin awọn enia mi ti di ìka, gẹgẹ bi abo ògongo li aginju.
4 Ahọn ọmọ-ọmu lẹ̀ mọ oke ẹnu rẹ̀ nitori ongbẹ: awọn ọmọ kekere mbere onjẹ, ẹnikan kò si bu u fun wọn.
5 Awọn ti o ti njẹ ohun didùndidùn nkú lọ ni ita: awọn ti a ti tọ́ ninu aṣọ-òdodó, gbá ãtàn mọra.
6 Nitori aiṣedede ọmọbinrin awọn enia mi tobi jù ẹ̀ṣẹ Sodomu lọ, ti a bì ṣubu ni iṣẹju, laisi iṣiṣẹ ọwọ ninu rẹ̀.
7 Awọn Nasire rẹ̀ mọ́ jù ẹ̀gbọn-owu, nwọn funfun jù wàra; irisi wọn pọn jù iyùn, apẹrẹ wọn dabi okuta Safire:
8 Oju wọn dudu jù ẽdu nisisiyi; a kò mọ̀ wọn ni ita: àwọ wọn lẹ mọ egungun wọn; o di gbigbẹ gẹgẹ bi igi.