1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Joeli ọmọ Petueli wá.
2 Gbọ́ eyi, ẹnyin arugbo, si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ na. Eyi ha wà li ọjọ nyin, tabi li ọjọ awọn baba nyin?
3 Ẹ sọ ọ fun awọn ọmọ nyin, ati awọn ọmọ nyin fun awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ wọn fun iran miràn.
4 Eyi ti iru kòkoro kan jẹ kù ni ẽṣú jẹ; ati eyi ti ẽṣú jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ; eyiti kòkoro na si jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ.
5 Ji, ẹnyin ọmùti, ẹ si sọkun; si hu, gbogbo ẹnyin ọmùti waini, nitori ọti-waini titun; nitoriti a ké e kuro li ẹnu nyin.
6 Nitori orilẹ-ède kan goke wá si ilẹ mi, o li agbara, kò si ni iye, ehin ẹniti iṣe ehin kiniun, o si ni erìgi abo kiniun.