12 Nitori ara Maroti nreti ire, ṣugbọn ibi sọkalẹ ti ọdọ Oluwa wá si ẹnu bode Jerusalemu.
13 Iwọ ara Lakiṣi, di kẹkẹ mọ ẹranko ti o yara: on ni ibẹrẹ ẹ̀ṣẹ si ọmọbinrin Sioni: nitori a ri irekọja Israeli ninu rẹ.
14 Nitorina ni iwọ o ṣe fi iwe ikọ̀silẹ fun Moreṣetigati: awọn ile Aksibi yio jẹ eke si awọn ọba Israeli.
15 Sibẹ̀ emi o mu arole kan fun ọ wá, Iwọ ara Mareṣa: ogo Israeli yio wá si Adullamu.
16 Sọ ara rẹ di apari, si rẹ́ irun rẹ nitori awọn ọmọ rẹ ẹlẹgẹ́; sọ apári rẹ di gbòro bi idì; nitori a dì wọn ni igbèkun lọ kuro lọdọ rẹ.