7 Iwọ ẹniti anpe ni ile Jakobu, Ẹmi Oluwa ha bùkù bi? iṣe rẹ̀ ha ni wọnyi? ọ̀rọ mi kò ha nṣe rere fun ẹni ti nrin dẽde bi?
8 Ati nijelo awọn enia mi dide bi ọta si mi: ẹnyin ti bọ́ ẹ̀wu ati aṣọ ibora kuro lọdọ awọn ti nkọja li ailewu, bi awọn ẹniti o kọ̀ ogun silẹ.
9 Obinrin awọn enia mi li ẹnyin ti le jade kuro ninu ile wọn daradara; ẹnyin ti gbà ogo mi kuro lọwọ awọn ọmọ wọn lailai.
10 Ẹ dide, ki ẹ si ma lọ; nitoripe eyi kì iṣe ibi isimi: nitoriti o jẹ alaimọ́, yio pa nyin run, ani iparun kikorò?
11 Bi enia kan ti nrin ninu ẹmi ati itanjẹ ba ṣeke, wipe, emi o sọ asọtẹlẹ̀ ti ọti-waini ati ọti-lile fun ọ; on ni o tilẹ ṣe woli awọn enia yi.
12 Ni kikó emi o kó nyin jọ, iwọ Jakobu, gbogbo nyin; ni gbigbá emi o gbá iyokù Israeli jọ; emi o si tò wọn jọ pọ̀ gẹgẹ bi agutan Bosra, gẹgẹ bi ọwọ́ ẹran ninu agbo wọn: nwọn o si pariwo nla nitori ọ̀pọlọpọ enia.
13 Ẹniti nfọ́ni ti dide niwaju wọn: nwọn ti fọ́, nwọn kọja lãrin bode, nwọn si ti jade lọ nipa rẹ̀: ọba wọn o si kọja lọ niwaju wọn, Oluwa ni yio si ṣe olori wọn.