Nah 2 YCE

Ìṣubú Ninefe

1 ATUNIKA de iwaju rẹ (Ninefe): pa ile-iṣọ mọ, ṣọ ọ̀na na, di àmurè ẹ̀gbẹ rẹ ko le, mura girigiri.

2 Nitori Oluwa tun pada si ọlanla Jakobu, gẹgẹ bi ọlanla Israeli: atunidanù ti tú wọn danù, nwọn si ba ẹka àjara wọn jẹ.

3 A sọ asà awọn ọkunrin alagbara rẹ̀ di pupa, awọn akin wọn wọ̀ odòdó: kẹkẹ́ ogun yio ma kọ bi iná li ọjọ ipèse rẹ̀, igi firi li a o si mì tìti.

4 Ariwo kẹkẹ́ ni igboro, nwọn o si ma gbún ara wọn ni ọ̀na gbigbòro, nwọn o dabi etùfu, nwọn o kọ́ bi mànamána.

5 On o ṣe aṣàro awọn ọlọla rẹ̀: nwọn o kọsẹ̀ ni irìn wọn; nwọn o yara si ibi odi rẹ̀, a o si pèse ãbo rẹ̀.

6 A o ṣi ilẹ̀kun odò wọnni silẹ, a o si sọ ãfin na di yiyọ́.

7 Eyi ti a ti fi idi rẹ̀ mulẹ li a o si dì ni igbèkun lọ, a o si mu u goke wá, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ yio fi ohùn bi ti oriri ṣe amọ̀na rẹ̀, nwọn a ma lù aiya wọn.

8 Ṣugbọn Ninefe li ọjọ ti o ti wà bi adagun omi: sibẹ̀ nwọn o salọ kuro. Duro, duro! ni nwọn o ma ke; ṣugbọn ẹnikan kì yio wò ẹhìn.

9 Ẹ ko ikogun fàdakà, ẹ ko ikogun wurà! ati iṣura wọn ailopin na, ati ogo kuro ninu gbogbo ohunelò ti a fẹ́.

10 On ti sòfo, o ti di asan, o si di ahoro: aiyà si yọ́, ẽkún nlù ara wọn, irora pupọ̀ si wà ninu gbogbo ẹgbẹ́, ati oju gbogbo wọn si kó dudu jọ.

11 Nibo ni ibugbé awọn kiniun wà, ati ibujẹ awọn ọmọ kiniun, nibiti kiniun, ani agbà kiniun, ti nrìn, ati ọmọ kiniun, kò si si ẹniti o dẹruba wọn?

12 Kiniun ti fàya pẹrẹpẹrẹ tẹrùn fun awọn ọmọ rẹ̀, o si fun li ọrun pa fun awọn abo kiniun rẹ̀, o si fi ohun ọdẹ kún isà rẹ̀, ati ihò rẹ̀ fun onjẹ agbara.

13 Kiyesi i, emi dojukọ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi, emi o si fi kẹkẹ́ rẹ̀ wọnni joná ninu ẹ̃fin, idà yio si jẹ ọmọ kiniun rẹ wọnni run: emi o si ke ohun ọdẹ rẹ kuro lori ilẹ aiye, ohùn awọn ojiṣẹ rẹ li a kì yio si tún gbọ́ mọ.

orí

1 2 3