Nah 1 YCE

1 Ọ̀RỌ-ÌMỌ̀ niti Ninefe. Iwe iran Nahumu ara Elkoṣi.

Ibinu OLUWA sí Ìlú Ninefe

2 Ọlọrun njowu, Oluwa si ngbẹsan; Oluwa ngbẹsan, o si kún fun ibinu; Oluwa ngbẹsan li ara awọn ọta rẹ̀, o si fi ibinu de awọn ọta rẹ̀.

3 Oluwa lọra lati binu, o si tobi li agbara, ni didasilẹ̀ kì yio da enia buburu silẹ: Oluwa ni ọ̀na rẹ̀ ninu ãjà ati ninu ìji, awọsanma si ni ekuru ẹsẹ̀ rẹ̀.

4 O ba okun wi, o si mu ki o gbẹ, o si sọ gbogbo odò di gbigbẹ: Baṣani di alailera, ati Karmeli, itànna Lebanoni si rọ.

5 Awọn oke-nla mì nitori rẹ̀, ati awọn oke kékèké di yiyọ́, ilẹ aiye si joná niwaju rẹ̀, ani aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.

6 Tani o le duro niwaju ibinu rẹ̀? tani o si le duro gba gbigboná ibinu rẹ̀? a dà ibinu rẹ̀ jade bi iná, on li o si fọ́ awọn apata.

7 Rere li Oluwa, ãbo li ọjọ ipọnju; on si mọ̀ awọn ti o gbẹkẹ̀le e.

8 Ṣugbọn ikún omi akunrekọja li on fi ṣe iparun ibẹ̀ na de opin, okùnkun yio si ma lepa awọn ọta rẹ̀.

9 Kili ẹnyin ngbirò si Oluwa? on o ṣe iparun de opin, ipọnju kì yio dide lẹrinkeji.

10 Nitori sã ti a ba ká wọn jọ bi ẹ̀gun, ati sã ti wọn iba mu amupara bi ọmùti, a o run wọn gẹgẹ bi koriko ti o ti gbẹ de opin.

11 Ẹnikan ti ọdọ rẹ jade wá, ti o ngbirò ibi si Oluwa, olugbìmọ buburu.

12 Bayi ni Oluwa wi; bi nwọn tilẹ pé, ti nwọn si pọ̀ niye, ṣugbọn bayi ni a o ke nwọn lulẹ, nigbati on o ba kọja. Bi mo tilẹ ti pọn ọ loju, emi kì yio pọn ọ loju mọ.

13 Nitori nisisiyi li emi o fà ajàga rẹ̀ kuro li ọrun rẹ, emi o si dá idè rẹ wọnni li agbede-meji.

14 Oluwa si ti fi aṣẹ kan lelẹ nitori rẹ pe, ki a má ṣe gbìn ninu orukọ rẹ mọ: lati inu ile ọlọrun rẹ wá li emi o ke ere fifin ati ere didà kuro: emi o wà ibojì rẹ; nitori ẹgbin ni iwọ.

15 Wò o lori oke nla ẹsẹ̀ ẹniti o mu ihìn rere wá, ẹniti o nkede alafia! Iwọ Juda, pa aṣẹ rẹ ti o ni irònu mọ, san ẹ̀jẹ́ rẹ: nitori enia buburu kì yio kọja lãrin rẹ mọ; a ti ké e kuro patapata.

orí

1 2 3