Nah 3 YCE

1 EGBE ni fun ilu ẹjẹ̀ nì! gbogbo rẹ̀ kun fun eké, ati olè, ijẹ kò kuro;

2 Ariwo pàṣan, ati ariwo kikùn kẹkẹ́, ati ti ijọ awọn ẹṣin, ati ti fifò kẹkẹ́.

3 Ẹlẹṣin ti gbe idà rẹ̀ ti nkọ màna, ati ọkọ̀ rẹ̀ ti ndán yànran si oke: ọ̀pọlọpọ si li awọn ẹniti a pa, ati ọ̀pọlọpọ okú; okú kò si ni opin; nwọn nkọsẹ̀ li ara okú wọn wọnni:

4 Nitori ọ̀pọlọpọ awọn panṣagà àgbere ti o roju rere gbà, iya ajẹ ti o ntà awọn orilẹ-ède nipasẹ̀ panṣaga rẹ̀, ati idile nipasẹ̀ ajẹ rẹ̀.

5 Kiyesi i, emi dojukọ́ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ká aṣọ itẹlẹ̀di rẹ li oju rẹ, emi o si fi ihòho rẹ hàn awọn orilẹ-ède, ati itiju rẹ hàn awọn ilẹ̀ ọba.

6 Emi o da ẹgbin ti o ni irira si ọ lara, emi o si sọ ọ di alaimọ́, emi o si gbe ọ kalẹ bi ẹni ifiṣẹlẹyà.

7 Yio si ṣe pe, gbogbo awọn ti o wò ọ yio sa fun ọ, nwọn o si wipe, A ti fi Ninefe ṣòfo: tani yio kẹdùn rẹ̀? nibo ni emi o ti wá olutùnu fun ọ?

8 Iwọ ha sàn jù No-ammoni, eyiti o wà lãrin odò ti omi yika kiri, ti agbara rẹ̀ jẹ okun, ti odi rẹ̀ si ti inu okun jade wá?

9 Etiopia ati Egipti li agbara rẹ̀, kò si li opin; Puti ati Lubimu li awọn olùranlọwọ rẹ.

10 Sibẹ̀sibẹ̀ a kó o lọ, o lọ si oko-ẹrú: awọn ọmọ wẹ́wẹ rẹ̀ li a fi ṣánlẹ̀ pẹlu li ori ita gbogbo; nwọn si di ibò nitori awọn ọlọla rẹ̀ ọkunrin, gbogbo awọn ọlọla rẹ̀ li a si fi ẹwọ̀n dì.

11 Iwọ pẹlu o si yó ọti; a o si fi ọ pamọ, iwọ pẹlu o si ma ṣe afẹri ãbò nitori ti ọta na.

12 Gbogbo ile-iṣọ agbara rẹ yio dabi igi ọpọ̀tọ pẹlu akọpọn ọpọ̀tọ: bi a ba gbọ̀n wọn, nwọn o si bọ si ẹnu ọjẹun.

13 Kiye si i, obinrin li awọn enia rẹ lãrin rẹ: oju ibodè ilẹ rẹ li a o ṣi silẹ gbaguda fun awọn ọta rẹ: iná yio jo ikere rẹ.

14 Iwọ pọn omi de ihamọ, mu ile iṣọ rẹ le: wọ̀ inu amọ̀, ki o si tẹ̀ erupẹ̀, ki o si ṣe ibiti a nsun okuta-amọ̀ ki o le.

15 Nibẹ̀ ni iná yio jo ọ run; idà yio ké ọ kuro, yio si jẹ ọ bi kòkoro: sọ ara rẹ di pupọ̀ bi kòkoro, si sọ ara rẹ di pupọ̀ bi ẽṣu.

16 Iwọ ti sọ awọn oniṣòwo rẹ di pupọ̀ jù iràwọ oju ọrun lọ: kokòro nà ara rẹ̀, o si fò lọ.

17 Awọn alade rẹ dabi eṣú, awọn ọgagun rẹ si dabi ẹlẹngà nla, eyiti ndó sinu ọgbà la ọjọ otutù, ṣugbọn nigbati õrùn là, nwọn sa lọ, a kò si mọ̀ ibiti wọn gbe wà.

18 Awọn olùṣọ agùtan rẹ ntõgbe, Iwọ ọba Assiria: awọn ọlọla rẹ yio ma gbe inu ekuru: awọn enia rẹ si tuka lori oke-nla, ẹnikan kò si kó wọn jọ.

19 Kò si ipajumọ fun ifarapa rẹ; ọgbẹ rẹ kún fun irora, gbogbo ẹniti o gbọ́ ihin rẹ yio pàtẹwọ le ọ lori, nitori li ori tani ìwa-buburu rẹ kò ti kọja nigbagbogbo?

orí

1 2 3