5 On o ṣe aṣàro awọn ọlọla rẹ̀: nwọn o kọsẹ̀ ni irìn wọn; nwọn o yara si ibi odi rẹ̀, a o si pèse ãbo rẹ̀.
6 A o ṣi ilẹ̀kun odò wọnni silẹ, a o si sọ ãfin na di yiyọ́.
7 Eyi ti a ti fi idi rẹ̀ mulẹ li a o si dì ni igbèkun lọ, a o si mu u goke wá, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ yio fi ohùn bi ti oriri ṣe amọ̀na rẹ̀, nwọn a ma lù aiya wọn.
8 Ṣugbọn Ninefe li ọjọ ti o ti wà bi adagun omi: sibẹ̀ nwọn o salọ kuro. Duro, duro! ni nwọn o ma ke; ṣugbọn ẹnikan kì yio wò ẹhìn.
9 Ẹ ko ikogun fàdakà, ẹ ko ikogun wurà! ati iṣura wọn ailopin na, ati ogo kuro ninu gbogbo ohunelò ti a fẹ́.
10 On ti sòfo, o ti di asan, o si di ahoro: aiyà si yọ́, ẽkún nlù ara wọn, irora pupọ̀ si wà ninu gbogbo ẹgbẹ́, ati oju gbogbo wọn si kó dudu jọ.
11 Nibo ni ibugbé awọn kiniun wà, ati ibujẹ awọn ọmọ kiniun, nibiti kiniun, ani agbà kiniun, ti nrìn, ati ọmọ kiniun, kò si si ẹniti o dẹruba wọn?