8 Ṣugbọn Ninefe li ọjọ ti o ti wà bi adagun omi: sibẹ̀ nwọn o salọ kuro. Duro, duro! ni nwọn o ma ke; ṣugbọn ẹnikan kì yio wò ẹhìn.
9 Ẹ ko ikogun fàdakà, ẹ ko ikogun wurà! ati iṣura wọn ailopin na, ati ogo kuro ninu gbogbo ohunelò ti a fẹ́.
10 On ti sòfo, o ti di asan, o si di ahoro: aiyà si yọ́, ẽkún nlù ara wọn, irora pupọ̀ si wà ninu gbogbo ẹgbẹ́, ati oju gbogbo wọn si kó dudu jọ.
11 Nibo ni ibugbé awọn kiniun wà, ati ibujẹ awọn ọmọ kiniun, nibiti kiniun, ani agbà kiniun, ti nrìn, ati ọmọ kiniun, kò si si ẹniti o dẹruba wọn?
12 Kiniun ti fàya pẹrẹpẹrẹ tẹrùn fun awọn ọmọ rẹ̀, o si fun li ọrun pa fun awọn abo kiniun rẹ̀, o si fi ohun ọdẹ kún isà rẹ̀, ati ihò rẹ̀ fun onjẹ agbara.
13 Kiyesi i, emi dojukọ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi, emi o si fi kẹkẹ́ rẹ̀ wọnni joná ninu ẹ̃fin, idà yio si jẹ ọmọ kiniun rẹ wọnni run: emi o si ke ohun ọdẹ rẹ kuro lori ilẹ aiye, ohùn awọn ojiṣẹ rẹ li a kì yio si tún gbọ́ mọ.