15 Ará, emi nsọ̀rọ bi enia; bi o tilẹ jẹ pe majẹmu enia ni, ṣugbọn bi a ba ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò si ẹniti o le sọ ọ di asan, tabi ti o le fi kún u mọ́.
16 Njẹ fun Abrahamu ati fun irú-ọmọ rẹ̀ li a ti ṣe awọn ileri na. On kò wipe, Fun awọn irú ọmọ, bi ẹnipe ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn bi ẹnipe ọ̀kan, ati fun irú-ọmọ rẹ, eyiti iṣe Kristi.
17 Eyi ni mo nwipe, majẹmu ti Ọlọrun ti fi idi rẹ̀ mulẹ niṣãju, ofin ti o de lẹhin ọgbọ̀n-le-nirinwo ọdún kò le sọ ọ di asan, ti a ba fi mu ileri na di alailagbara.
18 Nitori bi ijogun na ba ṣe ti ofin, kì iṣe ti ileri mọ́: ṣugbọn Ọlọrun ti fi i fun Abrahamu nipa ileri.
19 Njẹ ki ha li ofin? a fi kun u nitori irekọja titi irú-ọmọ ti a ti ṣe ileri fun yio fi de; a si ti ipasẹ awọn angẹli ṣe ìlana rẹ̀ lati ọwọ́ alarina kan wá.
20 Njẹ alarina kì iṣe alarina ti ẹnikan, ṣugbọn ọ̀kan li Ọlọrun.
21 Nitorina ofin ha lodi si awọn ileri Ọlọrun bi? Ki a má ri: nitori ibaṣepe a ti fi ofin kan funni, ti o lagbara lati sọni di ãye, nitotọ ododo iba ti ti ipasẹ ofin wá.