26 Nitori bi awa ba mọ̃mọ̀ dẹṣẹ lẹhin igbati awa ba ti gbà ìmọ otitọ kò tun si ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ mọ́,
27 Bikoṣe ireti idajọ ti o ba ni lẹrù, ati ti ibinu ti o muná, ti yio pa awọn ọtá run.
28 Ẹnikẹni ti o ba gàn ofin Mose, o kú li aisi ãnu nipa ẹri ẹni meji tabi mẹta:
29 Melomelo ni ẹ ro pe a o jẹ oluwa rẹ̀ ni ìya kikan, ẹniti o ti tẹ Ọmọ Ọlọrun mọlẹ ti o si ti kà ẹ̀jẹ̀ majẹmu ti a fi sọ ọ di mimọ́ si ohun aimọ́, ti o si ti kẹgan Ẹmí ore-ọfẹ.
30 Nitori awa mọ̀ ẹniti o wipe, Ẹsan ni ti emi, Oluwa wipe, Emi o gbẹsan. Ati pẹlu, Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀.
31 Ohun ẹ̀ru ni lati ṣubu si ọwọ́ Ọlọrun alãye.
32 Ṣugbọn ẹ ranti ọjọ iṣaju, ninu eyiti, nigbati a ti ṣí nyin loju, ẹ fi ara da wahala ijiya nla;