4 Nipa igbagbọ́ ni Abeli ru ẹbọ si Ọlọrun ti o san ju ti Kaini lọ, nipa eyiti a jẹri rẹ̀ pe olododo ni, Ọlọrun si njẹri ẹ̀bun rẹ̀: ati nipa rẹ̀ na, bi o ti kú ni, o nfọhùn sibẹ̀.
5 Nipa igbagbọ́ li a ṣí Enoku nipò pada ki o máṣe ri ikú; a kò si ri i, nitoriti Ọlọrun ṣí i nipò pada: nitori ṣaju iṣipopada rẹ̀, a jẹrí yi si i pe o wù Ọlọrun.
6 Ṣugbọn li aisi igbagbọ́ ko ṣe iṣe lati wù u; nitori ẹniti o ba ntọ̀ Ọlọrun wá kò le ṣai gbagbọ́ pe o mbẹ, ati pe on ni olusẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a.
7 Nipa igbagbọ́ ni Noa, nigbati Ọlọrun kilọ ohun ti koi ti iri fun u, o bẹru Ọlọrun, o si kàn ọkọ̀ fun igbala ile rẹ̀, nipa eyiti o dá aiye lẹbi, o si di ajogún ododo ti iṣe nipa igbagbọ́.
8 Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a ti pè e lati jade lọ si ibi ti on yio gbà fun ilẹ-ini, o gbọ́, o si jade lọ, lai mọ̀ ibiti on nrè.
9 Nipa igbagbọ́ li o ṣe atipo ni ilẹ ileri, bi ẹnipe ni ilẹ àjeji, o ngbé inu agọ́, pẹlu Isaaki ati Jakọbu, awọn ajogún ileri kanna pẹlu rẹ̀:
10 Nitoriti o nreti ilu ti o ni ipilẹ̀; eyiti Ọlọrun tẹ̀do ti o si kọ́.