2 Ẹniti o ṣe olõtọ si ẹniti o yàn a, bi Mose pẹlu ti ṣe ninu gbogbo ile rẹ̀.
3 Nitori a kà ọkunrin yi ni yiyẹ si ogo jù Mose lọ niwọn bi ẹniti o kọ́ ile ti li ọla jù ile lọ.
4 Lati ọwọ́ enia kan li a sá ti kọ́ olukuluku ile; ṣugbọn ẹniti o kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọrun.
5 Mose nitõtọ si ṣe olõtọ ninu gbogbo ile rẹ̀, bi iranṣẹ, fun ẹrí ohun ti a o sọ̀rọ wọn nigba ikẹhin;
6 Ṣugbọn Kristi bi ọmọ lori ile rẹ̀; ile ẹniti awa iṣe, bi awa ba dì igbẹkẹle ati iṣogo ireti wa mu ṣinṣin titi de opin.
7 Nitorina gẹgẹbi Ẹmí Mimọ́ ti wi, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 Ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu, bi li ọjọ idanwò li aginjù: