4 Lati ọwọ́ enia kan li a sá ti kọ́ olukuluku ile; ṣugbọn ẹniti o kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọrun.
5 Mose nitõtọ si ṣe olõtọ ninu gbogbo ile rẹ̀, bi iranṣẹ, fun ẹrí ohun ti a o sọ̀rọ wọn nigba ikẹhin;
6 Ṣugbọn Kristi bi ọmọ lori ile rẹ̀; ile ẹniti awa iṣe, bi awa ba dì igbẹkẹle ati iṣogo ireti wa mu ṣinṣin titi de opin.
7 Nitorina gẹgẹbi Ẹmí Mimọ́ ti wi, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 Ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu, bi li ọjọ idanwò li aginjù:
9 Nibiti awọn baba nyin dán mi wò, nipa wiwadi mi, ti nwọn si ri iṣẹ mi li ogoji ọdún.
10 Nitorina inu mi bajẹ si iran na, mo si wipe, Nigbagbogbo ni nwọn nṣìna li ọkàn wọn; nwọn kò si mọ̀ ọ̀na mi.