14 Nitori o han gbangba pe lati inu ẹ̀ya Juda ni Oluwa wa ti dide; nipa ẹ̀ya ti Mose kò sọ ohunkohun niti awọn alufa.
15 O si tún han gbangba jù bẹ̃ lọ bi o ti jẹ pe alufa miran dide gẹgẹ bi Melkisedeki,
16 Eyiti a kò fi jẹ gẹgẹ bi ofin ilana nipa ti ara, bikoṣe nipa agbara ti ìye ailopin.
17 Nitori a jẹri pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.
18 Nitori a mu ofin iṣaju kuro, nitori ailera ati ailere rẹ̀.
19 (Nitori ofin kò mu ohunkohun pé), a si mu ireti ti o dara jù wá nipa eyiti awa nsunmọ Ọlọrun.
20 Niwọn bi o si ti ṣe pe kì iṣe li aibura ni.