3 Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa wa Jesu Kristi.
4 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo nitori nyin, nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun nyin ninu Jesu Kristi;
5 Nitoripe nipasẹ rẹ̀ li a ti sọ nyin di ọlọrọ̀ li ohun gbogbo, ninu ọ̀rọ-isọ gbogbo, ati ninu ìmọ gbogbo;
6 Ani gẹgẹ bi a ti fi idi ẹrí Kristi kalẹ ninu nyin:
7 Tobẹ ti ẹnyin kò fi rẹ̀hin ninu ẹ̀bunkẹbun; ti ẹ si nreti ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi:
8 Ẹniti yio si fi idi nyin kalẹ titi de opin, ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn li ọjọ Oluwa wa Jesu Kristi.
9 Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.