1 ẸNIKẸNI ninu nyin, ti o ni ọ̀ran kan si ẹnikeji rẹ̀, ha gbọdọ lọ pè e li ẹjọ niwaju awọn alaiṣõtọ, ki o má si jẹ niwaju awọn enia mimọ́?
2 Ẹnyin kò ha mọ̀ pe awọn enia mimọ́ ni yio ṣe idajọ aiye? Njẹ bi o ba ṣepe a ó tipasẹ nyin ṣe idajọ aiye, ẹnyin ha ṣe alaiyẹ lati ṣe idajọ awọn ọ̀ran ti o kere julọ?
3 E kò mọ̀ pe awa ni yio ṣe idajọ awọn angẹli? melomelo li ohun ti iṣe ti aiye yi?
4 Njẹ bi ẹnyin ni yio ba ṣe idajọ ohun ti iṣe ti aiye yi, ẹnyin ha nyan awọn ti a kò kà si rara ninu ijọ ṣe onidajọ?
5 Mo sọ eyi fun itiju nyin. O ha le jẹ bẹ̃ pe kò si ọlọgbọn kan ninu nyin ti yio le ṣe idajọ larin awọn arakunrin rẹ̀?
6 Ṣugbọn arakunrin npè arakunrin li ẹjọ, ati eyini niwaju awọn alaigbagbọ́.
7 Njẹ nisisiyi, abuku ni fun nyin patapata pe ẹnyin mba ara nyin ṣe ẹjọ. Ẽṣe ti ẹnyin kò kuku gbà ìya? ẽṣe ti ẹnyin kò kuku jẹ ki a rẹ́ nyin jẹ?
8 Ṣugbọn ẹnyin njẹni ni ìya, ẹ sì nrẹ́ ni jẹ, ati eyini awọn arakunrin nyin.
9 Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn alaiṣõtọ kì yio jogún ijọba Ọlọrun? Ki a má tàn nyin jẹ: kì iṣe awọn àgbere, tabi awọn abọriṣa, tabi awọn panṣaga, tabi awọn alailera, tabi awọn ti nfi ọkunrin bà ara wọn jẹ́,
10 Tabi awọn olè, tabi awọn olojukòkoro, tabi awọn ọmuti, tabi awọn ẹlẹgàn, tabi awọn alọnilọwọgbà ni yio jogún ijọba Ọlọrun.
11 Bẹ̃ li awọn ẹlomiran ninu nyin si ti jẹ rí: ṣugbọn a ti wẹ̀ nyin nù, ṣugbọn a ti sọ nyin di mimọ́, ṣugbọn a ti da nyin lare li orukọ Jesu Kristi Oluwa, ati nipa Ẹmí Ọlọrun wa.
12 Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ère: ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn emi kì yio jẹ ki a fi mi sabẹ agbara ohunkohun.
13 Onjẹ fun inu, ati inu fun onjẹ: ṣugbọn Ọlọrun yio fi opin si ati inu ati onjẹ. Ṣugbọn ara kì iṣe ti àgbere, bikoṣe fun Oluwa; ati Oluwa fun ara.
14 Ṣugbọn Ọlọrun ti jí Oluwa dide, yio si jí awa dide pẹlu nipa agbara rẹ̀.
15 Ẹnyin kò mọ̀ pe ẹ̀ya-ara Kristi li ara nyin iṣe? njẹ emi o ha mu ẹ̀ya-ara Kristi, ki emi ki o si fi ṣe ẹ̀ya-ara àgbere bi? ki a má ri.
16 Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ẹniti o ba dàpọ mọ́ àgbere di ara kan? nitoriti o wipe, Awọn mejeji ni yio di ara kan.
17 Ṣugbọn ẹniti o dàpọ mọ́ Oluwa di ẹmí kan.
18 Ẹ mã sá fun àgbere. Gbogbo ẹ̀ṣẹ ti enia ndá o wà lode ara; ṣugbọn ẹniti o nṣe àgbere nṣẹ̀ si ara on tikararẹ̀.
19 Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ara nyin ni tẹmpili Ẹmí Mimọ́, ti mbẹ ninu nyin, ti ẹnyin ti gbà lọwọ Ọlọrun? ẹnyin kì si iṣe ti ara nyin,
20 Nitori a ti rà nyin ni iye kan: nitorina ẹ yìn Ọlọrun logo ninu ara nyin, ati ninu ẹmí nyin, ti iṣe ti Ọlọrun.