1. Kor 5 YCE

Paulu Ṣe Ìdájọ́ Lórí Ìwà Ìbàjẹ́

1 A nròhin rẹ̀ kalẹ pe, àgbere wà larin nyin, ati irú àgbere ti a kò tilẹ gburo rẹ̀ larin awọn Keferi, pe ẹnikan ninu nyin fẹ aya baba rẹ̀.

2 Ẹnyin si nfẹ̀ soke, ẹnyin kò kuku kãnu ki a le mu ẹniti o hu iwa yi kuro larin nyin.

3 Nitori lõtọ, bi emi kò ti si lọdọ nyin nipa ti ara, ṣugbọn ti mo wà pẹlu nyin nipa ti ẹmí, mo ti ṣe idajọ ẹniti o hu iwà yi tan, bi ẹnipe mo wà lọdọ nyin.

4 Li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa. Nigbati ẹnyin ba pejọ, ati ẹmí mi, pẹlu agbara Jesu Kristi Oluwa wa,

5 Ki ẹ fi irú enia bẹ̃ le Satani lọwọ fun iparun ara, ki a le gbà ẹmí là li ọjọ Jesu Oluwa.

6 Iṣeféfe nyin kò dara. Ẹnyin kò mọ̀ pe iwukara diẹ ni imu gbogbo iyẹfun di wiwu?

7 Nitorina ẹ mu iwukara atijọ kuro ninu nyin, ki ẹnyin ki o le jẹ́ iyẹfun titun, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ́ aiwukara. Nitori a ti fi irekọja wa, ani Kristi, rubọ fun wa.

8 Nitorina ẹ jẹ ki a ṣe ajọ na, kì iṣe pẹlu iwukara atijọ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu iwukara arankàn ati ìwa buburu; bikoṣe pẹlu aiwukara ododo ati otitọ.

9 Emi ti kọwe si nyin ninu iwe mi pe, ki ẹ máṣe ba awọn àgbere kẹgbẹ pọ̀:

10 Ṣugbọn kì iṣe pẹlu awọn àgbere aiye yi patapata, tabi pẹlu awọn olojukòkoro, tabi awọn alọnilọwọgbà, tabi awọn abọriṣa; nitori nigbana ẹ kò le ṣaima ti aiye kuro.

11 Ṣugbọn nisisiyi mo kọwe si nyin pe, bi ẹnikẹni ti a npè ni arakunrin ba jẹ àgbere, tabi olojukòkoro, tabi abọriṣa, tabi ẹlẹgàn, tabi ọmutipara, tabi alọnilọwọgbà; ki ẹ máṣe ba a kẹgbẹ; irú ẹni bẹ̃ ki ẹ má tilẹ ba a jẹun.

12 Nitori ewo ni temi lati mã ṣe idajọ awọn ti mbẹ lode? ki ha ṣe awọn ti o wà ninu li ẹnyin ṣe idajọ wọn?

13 Ṣugbọn awọn ti o wà lode li Ọlọrun nṣe idajọ wọn. Ẹ yọ enia buburu na kuro larin ara nyin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16