1 ATI emi, ará, nigbati mo tọ̀ nyin wá, kì iṣe ọ̀rọ giga ati ọgbọ́n giga ni mo fi tọ̀ nyin wá, nigbati emi nsọ̀rọ ohun ijinlẹ Ọlọrun fun nyin.
2 Nitori mo ti pinnu rẹ̀ pe, emi kì yio mọ̀ ohunkohun larin nyin, bikoṣe Jesu Kristi, ẹniti a kàn mọ agbelebu.
3 Emi si wà pẹlu nyin ni ailera, ati ni ẹ̀ru, ati ni ọ̀pọlọpọ iwarìri.
4 Ati ọ̀rọ mi, ati iwasu mi kì iṣe nipa ọ̀rọ ọgbọ́n enia, ti a fi nyi ni lọkàn pada, bikoṣe nipa ifihan ti Ẹmí ati ti agbara:
5 Ki igbagbọ́ nyin ki o máṣe duro ninu ọgbọ́n enia, bikoṣe ninu agbara Ọlọrun.
6 Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n larin awọn ti o pé: ṣugbọn kì iṣe ọgbọ́n ti aiye yi, tabi ti awọn olori aiye yi, ti o di asan:
7 Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n Ọlọrun ni ijinlẹ, ani ọgbọ́n ti o farasin, eyiti Ọlọrun ti làna silẹ ṣaju ipilẹṣẹ aiye fun ogo wa:
8 Eyiti ẹnikẹni ninu awọn olori aiye yi kò mọ̀: nitori ibaṣepe nwọn ti mọ̀ ọ, nwọn kì ba ti kàn Oluwa ogo mọ agbelebu.
9 Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ, pe, Ohun ti oju kò ri, ati ti etí kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ.
10 Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣi wọn paya fun wa nipa Ẹmí rẹ̀: nitoripe Ẹmí ni nwadi ohun gbogbo, ani, ohun ijinlẹ ti Ọlọrun.
11 Nitori tani ninu enia ti o mọ̀ ohun enia kan, bikoṣe ẹmí enia ti o wà ninu rẹ̀? bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o mọ̀ ohun Ọlọrun, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun.
12 Ṣugbọn awa ti gbà, kì iṣe ẹmi ti aiye, bikoṣe Ẹmí ti iṣe ti Ọlọrun; ki awa ki o le mọ̀ ohun ti a fifun wa li ọfẹ lati ọdọ Ọlọrun wá.
13 Ohun na ti awa si nsọ, kì iṣe ninu ọ̀rọ ti ọgbọ́n enia nkọ́ni, ṣugbọn eyiti Ẹmí Mimọ́ fi nkọ́ni; eyiti a nfi ohun Ẹmí we ohun Ẹmí.
14 Ṣugbọn enia nipa ti ara kò gbà ohun ti Ẹmí Ọlọrun wọnni: nitoripe wère ni nwọn jasi fun u: on kò si le mọ̀ wọn, nitori nipa ti Ẹmí li a fi nwadi wọn.
15 Ṣugbọn ẹniti o wà nipa ti ẹmí nwadi ohun gbogbo, ṣugbọn kò si ẹnikẹni ti iwadi rẹ̀.
16 Nitoripe tali o mọ̀ inu Oluwa, ti yio fi mã kọ́ ọ? Ṣugbọn awa ni inu Kristi.