14 Nitorina, ẹnyin olufẹ mi, ẹ sá fun ibọriṣa.
15 Emi nsọ̀rọ bi ẹnipe fun ọlọgbọn; ẹ gbà eyiti mo wi rò.
16 Ago ibukún ti awa nsure si, ìdapọ ẹ̀jẹ Kristi kọ́ iṣe? Akara ti awa mbù, ìdapọ ara Kristi kọ́ iṣe?
17 Nitoripe awa ti iṣe ọ̀pọlọpọ jasi akara kan, ara kan: nitoripe gbogbo wa li o jumọ npin ninu akara kan nì.
18 Ẹ wo Israeli nipa ti ara: awọn ti njẹ ohun ẹbọ, nwọn ki ha iṣe alabapin pẹpẹ?
19 Njẹ kini mo nwi? pe, ohun ti a fi rubọ si oriṣa jẹ nkan, tabi pe oriṣa jẹ nkan?
20 Ṣugbọn ohun ti mo nwi nipe, ohun ti awọn Keferi fi nrubọ, nwọn fi nrubọ si awọn ẹ̃mi èṣu, kì si iṣe si Ọlọrun: emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ba awọn ẹmi èṣu ṣe ajọpin.