13 Ẹ gba a rò lãrin ẹnyin tikaranyin: o ha tọ́ ki obinrin ki o mã gbadura si Ọlọrun laibori?
14 Ani ẹda tikararẹ̀ kò ha kọ́ nyin pe, bi ọkunrin ba ni irun gigun, àbuku ni fun u?
15 Ṣugbọn bi obinrin ba ni irun gigun, ogo li o jẹ fun u: nitoriti a fi irun rẹ̀ fun u fun ibori.
16 Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba dabi ẹniti o fẹran iyàn jija, awa kò ni irú aṣa bẹ̃, tabi awọn ijọ Ọlọrun.
17 Ṣugbọn niti aṣẹ ti mo nfun nyin yi, emi kò yìn nyin pe, ẹ npejọ kì iṣe fun rere, ṣugbọn fun buburu.
18 Nitori lọna ikini, mo gbọ́ pe, nigbati ẹnyin pejọ ni ijọ, ìyapa mbẹ lãrin nyin; mo si gbà a gbọ́ li apakan.
19 Nitoripe kò le ṣe ki o má si adamọ pẹlu larin nyin, ki awọn ti o daju larin nyin ba le farahàn.