20 Nitorina nigbati ẹnyin ba pejọ si ibi kanna, kì iṣe lati jẹ Onjẹ Oluwa.
21 Nitoripe nigbati ẹnyin ba njẹun, olukuluku nkọ́ jẹ onjẹ tirẹ̀, ebi a si mã pa ẹnikan, ọti a si mã pa ẹnikeji.
22 Kinla? ẹnyin kò ni ile nibiti ẹ o mã jẹ, ti ẹ o si mã mu? tabi ẹnyin ngàn ijọ Ọlọrun, ẹnyin si ndojutì awọn ti kò ni? Kili emi o wi fun nyin? emi o ha yìn nyin ninu eyi? emi kò yìn nyin.
23 Nitoripe lọwọ Oluwa li emi ti gbà eyiti mo si ti fifun nyin, pe Jesu Oluwa li oru ọjọ na ti a fi i han, o mu akara:
24 Nigbati o si ti dupẹ, o bù u, o si wipe, Gbà, jẹ: eyi li ara mi ti a bu fun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi.
25 Gẹgẹ bẹ̃ li o si mú ago, lẹhin onjẹ, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun ninu ẹ̀jẹ mi: nigbakugba ti ẹnyin ba nmu u, ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi.
26 Nitori nigbakugba ti ẹnyin ba njẹ akara yi, ti ẹnyin ba si nmu ago yi, ẹnyin nkede ikú Oluwa titi yio fi de.