25 Bẹ̃li a si fi aṣiri ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ̃li on o si dojubolẹ yio si sin Ọlọrun, yio si sọ pe, nitotọ Ọlọrun mbẹ larin nyin.
26 Njẹ ẽhatiṣe, ará? nigbati ẹnyin pejọ pọ̀, ti olukuluku nyin ni psalmu kan, ẹkọ́ kan, ède kan, ifihàn kan, itumọ̀ kan. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo lati gbe-ni-ro.
27 Bi ẹnikan ba fi ède fọ̀, ki o jẹ enia meji, tabi bi o pọ̀ tan, ki o jẹ mẹta, ati eyini li ọkọ̃kan; si jẹ ki ẹnikan gbufọ.
28 Ṣugbọn bi kò ba si ogbufọ, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ninu ijọ; si jẹ ki o mã bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọrọ.
29 Jẹ ki awọn woli meji bi mẹta sọrọ, ki awọn iyoku si ṣe idajọ.
30 Bi a bá si fi ohunkohun hàn ẹniti o joko nibẹ, jẹ ki ẹni iṣaju dakẹ.
31 Gbogbo nyin le mã sọtẹlẹ li ọkọ̃kan, ki gbogbo nyin le mã kọ ẹkọ ki a le tu gbogbo nyin ni inu.